Tolu Odebiyi di Musulumi apapandodo nitori ipo Gomina - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, July 3, 2017

Tolu Odebiyi di Musulumi apapandodo nitori ipo Gomina

Kii se iroyin tuntun mo pe ko din ni mejidinlogun awon eeyan ni won ti n mura sile lati dupo gomina ipinle Ogun bayii, to si je pe eni kan soso lo maa gba ipo naa bo ti le wu ko ri.

Tolu Odebiyi pelu Gomina Amosun
Lara awon to ti n mura sile lati dupo naa ni Ogbeni Tolu Odebiyi to je olori awon osise nipinle naa, eni toun naa n wa oju rere Gomina Amosun, bo tile je pe awon to n wa oju rere e le ni mesan an.

Orisirisi ona lawon eeyan yi si n gba lati le je ki Gomina Amosun fa owo won soke pe eyii ni ayanfe omo mi, eni ti inu mi dun si gidigidi,gege bi oro inu Bibeli se so nigba ti Joonu se iribomi tan fun Jesu.

Lara awon ona yi lo fa ti olori awon osise yi fi tele Gomina Amosun loo kirun ni Yidi to ti maa n kirun lodoodun, eyi to wa ladugbo Lantoro nilu Abeokuta, nitori pe oniwa irele ti yoo gbonran ni Amosun loun n wa.

Sugbon nkan to tun wa je iyalenu lojo naa ni bi okunrin naa ko se je ki iwaju ori e kanle gege bawon Musulumi se maa n se e lati sin Olorun won, kaka ko je ki ori e kanle, se lo n fi owo mejeeji dii lati ma je ki ori e kanle.

Ohun ti ko se e pamo ni pe Tolu Odebiyi lawon eeyan dajubo nitori iru e ko tii sele ri keni to sunmo Olorun ninu esin igbagbo bii okunrin yi tun lo maa se esin mi in nitori ipo.

Ohun tawon eeyan wa n so bayii ni pe bokunrin naa ba mo pe looto loun fee maa kirun, ko sunmo awon ojogbon ninu esin Islam, tabi ko be Gomina Amosun lati koo bi won se n kirun.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI