Ko tii seni to le so
ibi toro naa yoo yori si bayii, lori bi Gomina ipinle Ogun, Ibikunle Amosun se
n fojoojumo yo awon to fi sipo nitori Senato Solomon Adeola, iyen Yayi, gege bi
a tun se rii gbo lose to koja pe, Gomina Amosun tun ti yo okan lara awon alaga
garaaji nilu Abeokuta, Akeem Iyeru, eni ti won loo ko ipa to po ninu idibo to
gbe e wole lodun 2011 ati 2015.
AWIKONKO gbo pe
leyin ti Senato Yayi kuro nibi eto kan tawon obinrin gbe kale lose to lo lohun,
lo loo se abewo sawon osise garaaji to wa lagbegbe Ita-Oshin, tawon yen si kii
kaabo pe awon n gbadun e.
Se e kuku mo iwa
awon omo garaaji bi won se maa n se fawon ti won ba fee gbowo lowo e, pe baba
rere, baba kee, bo tile je pe ko kii denu won, sugbon ki won le ri owo gba, eyi
gan an lo fa ti won fi surubo Senato Yayi lakoko naa, toun naa si seleri fun
won pe oun yoo mu inu won dun toun ba wole gomina lodun 2019.
Ko pe ti Senato Yayi
kuro nibe lawon kan to sunmo Gomina Amosun ti se gbeborun fun un pe awon osise
garaaji Ita-Oshin gba Senato Yayi lalejo, o si ti seleri orisirisi fun won, bee
lo tun fun won lowo peluu.
Odi la gbo pe Gomina
Amosun, eni ti kii fe gbo oruko Senato yi seti gba oro naa, to si ranse pe
alaga garaaji yi, iyen Ogbeni Akeem Iyeru lati foro waa lenu wo pe ki lo ri l’obe
to fi wa iru sowo.
Eni kan to sunmo
ijoba ipinle Ogun, to gbe oro naa si AWIKONKO leti so pe lesekese ti Gomina
Amosun foju kan Iyeru lo pase pe ko kowe fipo alaga naa sile, ati pe oun ko fe
rii mo ni garaaji eyikeyi nilu Abeokuta nitori o ti gbabodi foun.
Bi e o ba gbagbe,
laipe yi ni Gomina da okan pataki to feran ju, to je amugbalegbe e, Ogbeni
Damilola Ogunpola duro leyin to gbo pe okunrin naa ti fee gbabodi, to si ti n
lo sepade po pelu Yayi, gbogbo bi won se lokunrin naa fee so tenu e l’Amosun
loun ko fee gboro lenu e.
Bakan naa la tun gbo
pe o yo awon alaga APC nijoba ibile to to meedogun nitori tiroyin kan si pe won
ti fee faramo Yayi, eni tawon eeyan ti n gbosuba fun un pe oun nipo Gomina Kan
lodun 2019.
Ko soun meji tawon
osise n beru bayii bi ko se pe won sora won lati soro to jo mo ti Yayi, nitori
pe bi eni bu ata si egbo lo ma n ri lara Gomina Amosun to ba gboruko Yayi.
No comments:
Post a Comment