Opo awon to wa nibi
ipade awon Gomina ile Yoruba, iyen Southwest Governors’ Forum ti won se lojo
Aje Monde ana, nigba ti Gomina Amosun gba gomina nla marun un lalejo nilu
Abeokuta tii se olu-ilu ipinle ogun loro naa si n ya lenu titi dasiko yi.
Awon to wa nibe lo le
royin ohun toju won ri, sugbon tenu won ko le royin tan lojo naa, nitori bi
Gomina ipinle Ekiti, Osokomale, Ogbeni Ayodele Fayose se gba okiki ola ati eye
to ye ki gomina Amosun to je oun gan an ni olugbalejo awon gomina mefa naa gba
nitori aseyori abajade ipade naa, eyi ti won so pe fun alaafia ile Yoruba
nipade naa wa fun.
Gege b’AWIKONKO se ri
bi gbogbo nkan se lo lojo naa, bo tile je pe awon osise gomina Amosun se
ojusaaju, ti won ko je ki gbogbo awon oniroyin wole sinu gbongan ti won ti
sepade alakoko won, yato sawon oniroyin kan ti won ti lo ogbon alumokoroyi lati
foruko sile nitori ajosepo won pelu awon osise ijoba naa.
Inu ogba MITROS to wa
ninu Ibara nipade naa ti waye, eyi to ye ko bere laago mesan an aaro, sugbon to
je pe aago mejila koja iseju marun ni won sese bere nitori awon gomina kan to
pee de.
Ko too di pe awon
gomina bere sii de niporuru okan ti koko ba Gomina Amosun nitori tawon Gomina
to n reti ko tete, ki won le bere ipade ti won tori e ya ojo nla naa soto.
Bi Gomina Amosun se n
wole, lo n jade, to n fi foonu e pe awon to n reti lati mo ibi ti won de,
sugbon bo se n pe lori foonu e, lo dabie pe ipe naa ko ja gaara, eyi lo faa to
fi n ranse pe awon osise e, pe ko pe awon dereba atawon to n mu won mona, lati
mo ibi ti won de.
Si iyalenu, Gomina
ipinle Ondo, Rotimi Akeredolu lo koko de ni nnkan bi aago mewaa koja iseju
meloo kan, lesekese ti Gomina ti gbo pe Gomina Akeredolu ti wa ninu ogba MITROS
naa, lo ti sare bo sita ninu gbongan to wa, to si sare loo fi erin pade, ko too
muu wole lo jokoo.
Bee ni won reti awon
Gomina to ku titi, sugbon nigba to maa di nnkan bii aago mewaa ku iseju
marundinlogbon lariwo Ambo, iyen Gomina Ambode tipinle Ekoo gbode kan, tawon
okada ti won n pe ni Machine Gun marun, ti won fi n sare se atona e
wole, ko pe too de ni Amosun ti sare loo pade oun naa lenu ona, to si muu wole
lo sibi to maa jokoo sii.
Ko ju iseju meeedogun
lo ti Gomina Ambode wole, nibi ti Gomina Amosun ti n ronu kaakiri, to n fi
foonu e monito awon alejo to n reti,
lo ba wole, bo se wole tan, lariwo ayo so lati iwaju OPIC to wa n’Ibara, tawon
eeyan si bere sii pariwo “OSOKOMOLE iwo la n reti, gomina daadaa”.
Lati ‘be la gbo pe
awon onilu bere sii filu korin tele Gomina ipinle Ekiti, Ogbeni Ayodele Fayose,
ti won n kii ni mesan an mewaa titi to fi wonu ogba tipade naa ti fee waye. Bo se
fee wole, lo tun duro juwo sawon eeyan to ferin alaafia ati ayo pade e.
Bo tun se wole, to
fee ya wo enu ona abawole gbongan, lo tun yi gilaasi jiipu Lexus e wale, to si
ki awon eeyan nibi tawon akoroyin lorisiri ti won ko faaye gba lati wole jokoo
sii, tawon yen naa si pariwo “OSOKOMOLE”.
Biroyin Gomina Fayose se kan si Gomina Amosun la gbo pe o ti ka kiji nibi to wa, to si sare bo sita lenu ona lati pade e, sugbon awon to ri bi Gomina ipinle Ogun se rerin pade elegbe e yi, ni won mo pe erin iyangi ti ko denu lo fi pade e, bee inu e dun pe o wa.
Opo awon eeyan ni won
ti ro pe Gomina Fayose ko nii yoju nibi ipade awon Gomina naa olosu meta-meta
naa, nitori to je pe oun nikan ni Gomina to wa lati inu egbe alatako, eni tawon
eeyan ro pe ko figba kan gba ti aare orileede yi, Muhammadu Buhari.
Dide ti Gomina Fayose
de yi, lo fee bi Gomina Amosun ninu sawon Gomina ipinle meji to je pe irin-ajo
won silu Abeokuta ko ju wakati kan si meji lo, iyen Gomina ipinle Oyo ati
Gomina ipinle Osun, nitori to rii pe itiju lo fee je pe eni tawon si n se iye
meji lori e tun saaju awon ore kori-kosun e de.
Eyi gan an lo fa ti
okan Gomina Amosun ko fi bee fi tara-tara bale mo, to je pe iseju-iseju lo n
lo, to m bo. Bo se n pe osise kan pe ko bawon mo ibi tawon Gomina meji to ku
de, bee lo n pe elomin in lati beere bakan naa.
Leyin bii wakati kan,
iyen ni nnkan bi aago mejila ku iseju mejila ni ariwo ilu mi in tun so nita,
tiroyin si kan si Gomina Amosun pe Gomina Ajimobi ti wa nitosi lo ti sare pe
igbakeji e, Yetunde Onanuga atawon amugbalegbe e kan bii Tolu Odebiyi atawon
min in lati pade e.
Gege bi ise awon Oyo,
ilu atorin lawon to tele gomina Ajimobi wa lati Oyo fi tele de enu ona kawon
olopaa too le won jade, ti Gomina Amosun si mu Gomina Ajimobi wole lati loo fi
aga to maa jokoo si han an.
"Nibo le de" la gbo pe
Gomina Amosun n beere lowo enikan lori foonu, bo tile je pe AWIKONKO ko sun mon
on lati beere, sugbon to ye wa pe Ogbeni ni gomina n beere ibi to de, sugbon si
iyalenu, ko ju iseju mewaa ti Gomina Ajimobi wole, ni Gomina Amosun tun sare
jade senu ona pelu awon isongbe e lati pade Ogbeni Rauf Aregbesola tipinle
Osun.
Bo tile je pe inu e
ko fi bee dun lori bawon gomina mejeeji se pee de, sugbon tayo atidunnu la rii
pe Amosun fi mu won wole, ti won si sepade won fun bii ogoji iseju ko too di pe
won jade lati ya foto, nibi tawon eeyan tun ti raaye gboriyin fun Osokomale
tipinle Ekiti, toun naa si fayo dawon lohun.
Gbogbo bi won se n ki
Gomina Ayodele Fayose lojo naa ni ko fi bee dun mo Gomina Amosun ninu, nitori
to ti ro pe oun gan an lo ye ki won yin, ki won gbosuba fun pe oun loun gbawon
eeyan naa lalejo nipinle oun, sugbon oro ko ri bee.
No comments:
Post a Comment