Oogun owo ni Popoola atawon ore e fe se, ogba ewon ni won ti bara won - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, July 20, 2017

Oogun owo ni Popoola atawon ore e fe se, ogba ewon ni won ti bara won

Boroboro lawon ore meta towo olopaa ipinle Ogun te lose to koja yi ti won nise ki won ta ori oku ni won yan laayo ni ti won, sugbon tasiri won tu lakoko ti won n bo lati ibi ti won ti loo wu ori oku n ka ni tesan olopaa to wa ni Eleweran nilu Abeokuta.

Saibu Popoola, Aliu Ajiroba ati Jimoh Ijiola lawon odaran naa ti won so pe won ti ka gbogbo ise ti won ti n se sita fawon olopaa leyin towo te won ti won si ko won de tesan.

Gege bi iroyin to te AWIKONKO lowo se so, ori okada ni Saibu ati Aliu wa kawon olopaa too da won duro lagbegbe Idagba Olodo loju ona Aiyetoro, ati pe baagi ti won gbe dani lo fu awon olopaa lara, ti won si gba a yewo.

Lakoko ti won lawon olopaa n foro wa won lenu wo lati mo ibi ti won ti n bo ati pe ki lo wa ninu baagi ti won gbe dani, ni won so pe won ko ri oro gidi kan so, to si je kawon olopaa fura si won pe ara won ko mo pelu bi won se n soro.

Lakoko tawon odaran meteeta n b’AWIKONKO soro lopin ose to koja, Jimoh Ijiola so pe Saibu ati Aliu ni koba oun nitori pe se ni won so fawon olopaa pe oun loun gbe ori oku fun won, eyi ti ko ri bee.

Ninu oro e, o so pe “Ise oko ni n se. Ile ni mo wa nigba ti won waa mu mi. Emi ko ni gbe ori eeyan naa fun won. orileede olomiran Benini lati loo wu oku, ti a si ge ori e. ko si nnkan meji ti a fee fi se ju oogun owo lo.

“Kii se akoko re e ta maa n ge ori eeyan ati pe o lawon to maa n ra lowo wa. Sugbon eyi ti a loo ge yi, mo ti so fun won pe ki won toju e daadaa, pe tasiko ba to a maa lo fi se oogun owo taa fee loo fun. Sugbon nise ni won so fun awon olopaa pe emi ni mo ko ori mejeeji na fawon. Iro ni won pa mo mi.”

Nigba toun n soro, Abimbola Oyeyemi to je agbenuso funleese olopaa, o ni bi kii baa se pe awon olopaa naa dawon eeyan yi duro ni, won ko ba ti na papa bora, sugbon oro ti won bi won lo je ki won tete fura pe nnkan eru wa ninu apo ti won gbe dani.

O ni Aliu ati Saibu loo mu awon olopaa lo sile Jimoh nitori nnkan to so fun won ni pe oun loga won to ko awon ori naa fun won.

Abimbola so pe leyin tawon ba pari iwadii won lawon yoo to gbe won lo sile ejo, nitori pe Komisana olopaa, Ahmed ti pase pe kawon olopaa to n sise iwadii, iyen SCIID gba ise naa se.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI