Ogun esu re o; Sikiru n ko ibasun fomo e omodun mejila karakara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, July 25, 2017

Ogun esu re o; Sikiru n ko ibasun fomo e omodun mejila karakara

Bawon eeyan se n so pe kii soju lasan, bee lawon min in n so pe ise owo e lo n daa lejo, iyen baba eni odun mokanlelogoji kan ti won poruko e ni Sikiru Odejide, eni ti won so pe ojoojumo lo n ko ibasun fomo e, omdun metala.

Gege b’AWIKONKO se gbo, iya omo naa taa foruko bo lasiri la gbo pe o loo so fawon olopaa leyin tomo e loo foro naa to leti pe kini abe baba oun ti su oun lati maa gba lojoojumo, ati pe boun ko ba tete sa kuro lodo e, o seese ko fi kini naa yo ifun oun sile.

Ohun taa gbo ni pe, iya omo naa ti kuro lodo Sikiru lati nnkan bi odun marun leyin laasigbo kan ti won jo fa, sugbon se ni Sikiru so pe ko le gbe omo oun lo, to ba mo pe oun n lo, eyi lon faa ti won lomo naa fi wa lodo to n toju e.

Iyalenu lo je nigba to di osu kejila odun to koja, ti Sikiru pe omo e pe oun fee ri, omo ti won so pe omu e sese bere sii yo ni, to si kii mole, to fipa baa lo po. Latigba naa la gbo pe Sikiru ti n ba omo bibi inu e lajosepo, to si maa n so fun un pe ojo to ba soo sita loun maa pa danu.

Ekun ojoojumo la gbo pe omo naa ti ko tii koja ipele keji nileewe girama lo maa sun, sugbon ti ko seni to le soro naa fun. Sugbon nigba to ya tawon araadugbo rii pe oyan omo naa ti n tobi ju ojo ori e lo, lo je ki won tee ninu, to si salaye fun won.

Awon araadugbo naa la gbo won gba omo naa lamoran pe ko loo fi to mama e leti nibi to wa, ko too di pe o lo. Bomo naa se teko leti loo ba iya e nibi to n gbe, iyen lagbegbe Ijesatedo nipinle Ekoo ree, to si salaye gbogbo itu ti baba e fabe e pa lojoojumo pelu ihale iku mon on.

Bi mama omo yi se gboro ti omo e so kale, lo ba kawo lori pe kawon araadugbo gba oun, nitori koto aye ti won fee ju oun si.

Nibe lawon kan ti gboun naa lamoran pe ko ma sedajo lowo ara e, ko tete loo foro naa to awon olopaa leti, ki won le foju e bale ejo. Idi niyii tobinrin naa fi gba tesan to wa ni Sango ipinle Ogun lo lati loo fejo sun.

Iyalenu loro naa je nigba ti DPO to n soju Sango, iyen Ogbeni Akinsol,a Ogunwale gbo, to si ko soko pelu awon olopaa e lo sadugbo Onihale, Ifo nibi ti won lokunrin naa n gbe pelu omo e yii. Inu yara nibi to jokoo si ni won so pe won ti muu.

Orisirisi aheso la gbo pe o jade latari basiri Sikiru se tu sita, nitori bawon kan se n so pe iya to fi n je omo naa ko see fenu so tan, bee lawon kan n so pe ko sese maa see, nigba tawon kan an so pe awon mo on si, sugbon tawon ro pe idunnu omo yi ni.

Bo tile je pe se ni Sakiru dibon bi eni ti mo nnkan to n sele nigba ti won lawon olopaa loo mu nile, sugbon nigba to de tesan naa la gbo pe se loo so pe kawon olopaa se oun jeje, nitori ise esu ni. O loun ko mo nnkan to n ko soun ninu lati lo maa ba omo bibi inu oun lasepo. Bee lo ni kawon omo Naijiria foju aanu wo oun.

Nigba to n soro agbenuso funleese olopaa, Abimbola Oyeyemi so pe boun ba loun ko riru isele naa, oun tan awon araalu je ni, nitori pe ojoojumo lo n sele, eni towo palaba e ba segi lawon maa foju e han.

O niru Sikiru si po repete laarin awujo, sugbon awon araalu lo nise lati se, nitori bi won ko ba foro naa to awon olopaa leti, ko seese ki won mo nnkan to n lo. O wa seleri pe laipe lai jina, Sikiruu yoo foju bale ejo nitori pe komisana awon, Iliyasu ti tare e sojo ajo to n ri soro lilo omo nilokulo lati tesiwaju ninu ejo naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI