Afaimo ki awon alale
ma dide ibinu sawon to sagbateru iku Oba alaye kan nijoba ibile Yewa South, Oba
Patrick Oyeniran Fasinu to je Olowo tilu Owo latari bi won se so pe awon kan lo
wa nidi isele naa.
Oba Olowo |
Bo tile je pe owo
olopaa ipinle Ogun ti te Bolaji, to je okan lara awon to seku pa Oba Fasinu, ti
won si tun ti mu awako e sahamo lati foro waa lenu wo nitori ti won so pe aso
to kangun si eegun lo n je jepe, eni ti won so pe ohun lo ri Kabiyesi gbeyin.
Gege b’AWIKONKO se
gbo, ko ju iseju marun un ti won so pe Kabiyesi ja awako e sile, lawon odaran
naa da kabiyesi lona lagbegbe abule Ijako-Isagbo ni Oke-Odan, ti won si saa
lada titi to fi ku ni nnkan bi aago mewaa ale Ojoru Wesde to koja yii.
Won ni ero okan awon
eeyan yi ni pe kabiyesi naa ko le ku tan, o si seese ko ji pada, eyi lo faa ti
won so pe won tun dana sun un mo inu moto e lale ojo naa, ki won too na papa
bora.
Awon ti won n koja
lo lasiko isele naa, ni won so pe won ko le duro lati gba kabiyesi sile, ati pe
nise lawon eeyan naa sa asala fun emi won, ki won ma baa da emi ti won naa
legbodo, sugbon leyin tawon eeyan naa salo tan la gbo pe awon eeyan bere sii
yoju lati mo iru eeyan ti eni ti won dana sun je.
Igba ti won sunmo
ibi ajoku moto naa ni won too ri pe Kabiyesi lo wa nibe, lesekese ni won ti
bere sii royin iku naa kaakiri ko too di pe awon oloye atawon ebi Kabiyesi gbo.
AWIKONKO gbo pe bi
won se gbo ni won ti loo foro naa to awon olopaa leti lati le sewadi awon to wa
nidi isele naa, sugbon lojo keji la gbo pe owo awon odo abule te Bolaji, eni ti
won loo sonu sinu igbo, to si n wa ona lati lo.
Bo tile je pe won ni
se ni Bolaji towo te yi, eni ti won pe ilu Ekoo lo ti tele awon iko e to waa
seku pa kabiyesi so pe oun ko mo nnkan kan nipa isele naa, sugbon leyin tiya
dun un daadaa lo jewo pe ki won se oun jeje, o leni to ran awon.
Gbogbo oro ti won ni
Bolaji so kale niwaju Baale ilu Ogbo, nijoba ibile Ipokia ni won ti mo pe ise
agbero lo n se, ati pe awon to ran awon nise naa ti so pe leyin tawon ba pa
kabiyesi tan, kawon tun dana sun un patapata.
Ibinu ni won fi mu
Bolaji lo si tesan awon olopaa ekun Ipokia ko too di pe won gbe e lo si Ilaro
lati tubo loo foro waa lenu siwaju sii. Sugbon ni bayii, AWIKONKO gbo pe
Elweran ni Bolaji wa bayii.
Omoba Mathew Olaolu
fasinu to je aburo kabiyesi to doloogbe nigba to n b’AWIKONKO soro nipa isele
naa je ko di mimo pe lati nnkan bi odun ketala ti kabiyesi ti gbade ni wahala orisirisi
ti n sele laarin ilu.
O so pe ojoojumo ni
won n gbe kabiyesi lo sile ejo nitori wahala to wa laarin eya Anago ati Ogu,
pelu bi won se so pe ijoba ipinle Ogun gba ile won fun dida oko sii, to si je
pe igbagbo won ni pe kabiyesi ti gbowo abetele lowo ijoba, eyi ti ko je so
ohunkohun lati fi tako ijoba to gbale lowo awon to nii. Bee lo so pe ejo naa si
wa ni kootu kan l’Ota.
Okan lara awon oloye
nilu naa, Oloye Adetunji Iroko sapejuwe Oba Fasinu gege bi eni ti kii fa
wahala, to tun ni iberu Olorun lokan. O nilosiwaju ati idagbasoke ilu naa lo je
kabiyesi logun ati pe lojo tisele naa sele, ipade awon oba lo ti n bo.
Agbenuso ileese
olopaa ipinle Ogun, Abimbola Oyeyemi so pe iwadii si n lo lowo lati mu awon
odaran naa bale, kawon si le foju won bale ejo. O ni ko sidajo ti olopaa fee se
bi ko se pe ki adajo pasee.
Bee lo gbawon araalu lamoran pe ti won ba kefiri awon odaran ladugbo won, ki won tete fi to awon olopaa leti, ki won ma se pinu lati se idajo lowo ara won nitori pe ijiya wa fun awon to ba se bee.
No comments:
Post a Comment