Mo feran lati maa ja moto gba - Obafemi - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, July 10, 2017

Mo feran lati maa ja moto gba - Obafemi

Odomokunrin kan, Osho Obafemi ti so pe ise toun mo ju, to si tun rorun foun ju ni jija moto gba, ogba awon olopaaa ni Eleweran niluu Abeokuta  lokunrin naa ti n tu asiri ara e nigba ti won safihan e.

Obafemi
Gege bi AWIKONKO se gbo, okunrin kan ti won poruko e ni Adebayo Adekoya loo fejo sun awon olopaa lojo keji osu kerin odun yi pe awon kan da oun lona won si gba moto Toyota Corolla toun sese ra, toun ko tii gba nomba si lowo oun.

Ohun taa gbo pe ni pe agbegbe Ikoto n’Ijebu Ode lokunrin naa n gbe, sugbon Sagamu lo so pe won ti gba moto naa lowo oun ni nnkan bi aago mesan ale ojo naa. O ni pelu ibon ni won fi ri moto naa gba.

Loju ese lawon olopaa ti bere igbese lori bi won se le ri awon eeyan naa mu, ti Olorun si fun won se, towo si te Obafemi nilu Ibafo. Iyalenu lo je nigba tawon olopaa mu, bo tile je pe won loo koko bawon olopaa sagidi sugbon to mu won debi to n ko awon moto to ba ja gba si.

Olorun lo mo awon to loo se gboborun fawon ti won jo n sise pelu Obafemi, nitori gbara ti won so pe won gbo pe owo olopaa ti te Obafemi ni won ti na papa bora ki on too de be. Moto merin otooto ni won ba ninu ogba ti won n ko awon moto si.

Lesekese ni won ni Obafemi ti so pe ki won se oun jeje, oun si maa jewo awon ise toun atawon toku oun ti joo se seyin, sugbon titi di asiko yi, awon olopaa si n wa awon toku.

AWIKONKO gbo pe awon moto ti won ri gba lowo Obafemi ni Toyota Corolla alawo dudu, Jiipu Pilot Honda, Almera Nissan ati Toyota Corolla alawo eeru.

Nigba to n jeri soro naa, Komisana olopaa so pe ki eto aabo tubo le kesejare lawon olopaa se n sise tosan-toru, eyi lo si fa kasiri awon odaran maa tu sawon lowo. O ni lesekese tawon araalu ba ti ta awon lolobo lawon ti maa n gbe igbese.

Bakan naa lo so pe kawon eeyan ma se maa gboju fo awon ajoji ti won ba salabapade ladugbo won da, ki won tete foro naa to awon olopaa leti, nitori aabo emi ati dukia awon araalu lo je awon olopaa logun.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI