Lojo Itunu Aawe; Foonu Olu Itori poora nile Gomina Amosun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, July 3, 2017

Lojo Itunu Aawe; Foonu Olu Itori poora nile Gomina Amosun

Kayeefi loro foonu Oba Akorede Akamo, Olu Itori nijoba ibile Ewekoro si n je fawon eeyan nitori ti won so pe nile Gomina ipinle Ogun, Ibikunle Amosun to wa ni Ibara ni foonu naa to poora lojiji lojo odun itunu aawe.

Oba Akamo
Titi di bi a ti n koroyin yi la gbo pe inu Oba naa ko dun rara nitori awon ise Pataki to ti se sori awon foonu e to je olowo nla mejeeji ti ko seni to le so bo se rin in lojiji.

 “Ta lo ko foonu mi, wia is mai foonu” nibeere ti Oba Akamo n beere lowo awon ti won jo jokoo sibi kan naa. Bi ala loro foonu yi se je fun Kabiyesi atawon agbaagba leka oselu, to fi mo Gomina Amosun funra e lojo naa.

Gege bi AWIKONKO se gbo, ile Amosun to wa ni Ibara nisele naa ti waye lojo Aiku Sande to koja lo lohun, iyen lojo odun Itunu Aawe nigba tawon eeyan loo ki Gomina nile lati baa se odun naa, paapaa bo se je pe opo awon eeyan lo n wa oju rere e fun ti idibo odun 2019 to m bo lona.

Ki Gomina too de lawon oba alade, osise ijoba, awon komisana, awon alabasise po Gomina atawon oloselu nipinle Ogun ti loo duro de e nile e lojo naa, ti won si n reti e pe ko ni pee de.

Bi Amosun se n bo sile ninu moto e, ni won lawon kan ti sare loo so fawon to wa ninu ile pe Gomina ti n bo, ti gbogbo won si bere si nii sunra ki titi to fi wonu ile. Bo se wole ni won lawon eeyan jankan-jankan ti lo n ki, eyi ti won ni ko yo Olu Itori sile.

Won ni boju Amosun ati Olu-Itori se se merin ni Kabiyesi sare dide nibi to jokoo si, ti ko si ko foonu e olowo nla meji ti won lori tebu to wa niwaju e lo koo si. Gbogbo ero okan e ni pe ko seni to lee ji foonu oun, lai mo pe awon kan n so o.

Iyalenu lo je nigba ti won ni Olu Itori pada sibe to si wa awon foonu e mejeeji yi ti, ti won si n wo ileele boya se loo jabo, sugbon titi di bi a ti n koroyin yi, a ko tii gbo pe won ti ri awon foonu naa.

Lesekese loro naa ti kan sawon eeyan pe won n wa foonu Oba Itori, won ti e so pe ebun wa fun eni to ba bawon ri, sugbon ti won ko rii.

Bo tile je pe won ni Kabiyesi ti n fi nnkan panu koro naa too sele, sugbon titi to fi kuro nibe lojo naa, ironu foonu yi lo gbe e kuro lojo naa, ti ko si je ki ounje, omi ati oti lo lenu e mo.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI