Eyi ni bi Odunlade Adekola ati Mista Latin se bo lowo iku lojo Satide to koja yii - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, July 24, 2017

Eyi ni bi Odunlade Adekola ati Mista Latin se bo lowo iku lojo Satide to koja yii

Eyi kii se fiimu agbelewo rara, tabi itan aroso to m bo lona, ti yoo jade laipe, ko ri bee nitori pe die lo ku kawon agbebon pa awon ilumooka osere tiata tawon aye si n gba ti won lasiko yii.

Foto ti won ya lojo naa
Titi di bi a ti n sakojopo iroyin yi loro naa si n dabi fiimu agbelewo ti won n se fawon gbajumo osere tiata meji nni, Omoba Bolaji Amusan topo mo si Mista Latin ati Odunlade Adekola tawon eeyan tun un n pe ni Monday Dagboru latari bi won se salabapade awon igara olosa ti won fee demi won legbodo.

Bii kii ba a se pe aabo Olorun to daju wa lori awon mejeeji ni, bo ya nnkan ti a ko yi ko la o ba maa ko, nitori o see se ki iroyin ibanuje tun ti sokale sagboole awon oni tiata, sugbon ti Olorun Oga Ogo ko faaye gba.

Gege bi AWIKONKO se gbo, ojo Abameta Satide to koja lo lohun nileese Globacom eyi ti Ogbeni Mike Adenuga je oludari gbe eto kan kale, ti won si fiwe pe gbajumo osere mejeeji naa lati wa nibe.

Nibi eto naa la gbo pe won ti dawon mejeeji lola, tawon ololufee tun bawon mejeeji ya foto pelu awon osere tiata min in ti won jo lo sibi eto naa, ti won se nilu Ijebu Ode ti oluleese naa wa.

AWIKONKO gbo pe nigba tawon Mista Latin ati Odunlade Adekola maa fi kuro nibi eto yi lojo naa, ile ti n su, nitori ti won so pe nnkan bi aago meje ale ni won kuro nibe, ti won si teko leti.

Idunnu tawon osere mejeeji yi pelu awon isongbe won ti won tele won lo ba bo lojo naa, moto Odunlade Adekola to je Toyota Avensis la gbo pe o wa niwaju, ti moto Mista Latin, Toyota Camry si n bo leyin e pelu ayo.

Nigba ti won maa de agbegbe Ilisan si Sagamu la gbo pe Odunlade Adekola sakiyesi awon kan ti won gbegi nla dina pelu ibon lowo won, ero okan ni pe awon olopaa ni, sugbon bo se n summon on won lo rii pe iduro won yato si tawon olopaa atawon soja to maa n gbe igi dina.

Lesekese la gbo pe o te ijanu oko e, iyen bureeki (brake), o si fee yi pada lati salo, ko si loo gba ona ibomi in, sugbon bawon agbebon naa se rii pe moto to ti fee sun mon on won fee yi pada ni won ba dabon bo moto naa, ati taya ese e.

Eyi lo faa ti moto naa ko fi le lo mo, pelu eru la gbo pe Odunlade Adekola fi sa bo sile ninu moto naa, to si mu ori wonu igbo lai mu nkan kan jade. Gbogbo ara moto e yi la gbo pe won fibon baje.

Mista Latin ni ti e ko kuku mo nnkan to n sele ni tie, sugbon bo se maa wo iwaju nigba to sun mo ibi ti moto Odunlade wa, lo sakiyesi pe nnkan ti sele, boun naa se ni koun yi ori moto e pada lati salo lawon igara olosa naa ba tun dabon bo moto tie naa.

Loju ese loro di bolo o yago, ti Mista Latin atawon to wa ninu moto pelu e sa boole ninu moto naa, ti gbogbo won mu ori wonu igbo, ti eni kan ko ri eni keji, inu igbo ni won ti pada pade ara won nibi ti won ti n ronu bawon yoo se yo ninu wahala naa.

Fun bii wakati meji la gbo awon eeyan naa fi wa ninu igbo, ti won ronu ibi tawon yoo gba lati salo, sugbon to je pe awon eso oju-lalakan-fi-n-sori, iyen awon fijilante ni Olorun lo lati yo won kuro ninu laasigbo naa.

Awon Fijilante naa la gbo pe won gbe won lo sile iwosan ijoba to wa niluu Sagamu lati toju won, nitori ti won so pe opo awon eeyan ti won jo wa papo ninu moto naa ni won farapa yan-na-yan-naa.

Nigba to n soro naa sita fawon eeyan, Mista latin so pe se loro naa da bi fiimu tawon n se ni, ati pe iru e ko tii sele sawon ri, sugbon eyi to sele lojo naa ko awon lekoo repete.

O loun dupe lowo Olorun pe awon eru won bii owo, dukia atawon foonu won ni Olorun lo lati fi ropo emi awon, nitori pe leyin tawon sa wonu igbo lawon igara olosa naa ko gbogbo nnkan ini won tawon ko ranti ko lasiko tisele naa waye.

Agbenuso fun ileese olopaa, Abimbola Oyeyemi nigba to n soro lori isele naa, o so pe lesekese tawon ti gbo sisele naa lawon ti bere igbese lati sewadi awon to le wa nidi e.

O loun mo pe lai pe lai jina, owo awon olopaa yoo te awon igara olosa naa, tawon yoo si foju won ha fawon araalu, nitori pe aabo emi ati dukia awon araalu lo je awon olopaa logun nkan min in lo.

Ni bayii, ohun ti a gbo ni pe, ara awon eeyan naa ko tii lele, nitori se nisele naa si n dabi ala ati fiimu loju won. AWIKONKO gbo pe se leru si n bawon eeyan naa lati jade sita.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI