Kii se iroyin tuntun
mo pe gbajumo osere tiata nni, Oloogbe Yomi Ogunmola ti papoda, sugbon nkan to
si n je kawon eeyan si maa ranti e dasiko yi ni awon ipa to ti ko laarin awon
egbe osere tiata lorileede yi ko too ku.
Oloogbe Yomi Ogunmola |
Fun awon to ba mo
okunrin oloogbe yi daadaa, yoo mo pe iru e ko pe meji nigba aye e, ko da, bawon
eeyan se n kan saara si Odunlade Adekola lasiko yi, bee naa ni won n gbosuba
kare fun Yomi Ogunmola nigba naa.
Lara awon fiimu
tokunrin naa ti ko pa ko too ku ni “Ayo ni mo fe” se lodun 1994, sinima naa lo
si tun je ki okiki won kan jake jado orileede yi, to fi mo oke okun.
Bee naa lo tun kopa
to joju ninu fiimu “Ago Kan Oru” lodun 2003, ati pe Yomi Ogunmola gangan lo
dari fiimu naa, eyi lo fa a tawon ololufe e, paapaa awon osere tiata to sunmo,
atawon ti won jo sise po ko se le gbagbe e titi di bi a ti n koroyin yi.
Ojo Aje Monde ose to m bo,
iyen ojo ketadinlogun ni yoo pe odun merinla gbako ti Oloogbe Yomi Ogunmola, to
je egbon fun Peju Ogunmola file saso bora, bo tile je pe ojo keerindinlogun ni
saseye ikeyin pelu ale awon osere tiata (artistes’ night) fun un nile e to wa
ni Abule Egba nipinle Ekoo, iyen lodun 2003.
No comments:
Post a Comment