Kennery 4 Praise fee sekojade awo orin tuntun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, July 14, 2017

Kennery 4 Praise fee sekojade awo orin tuntun

Gbogbo eto lo ti fee to tan fun ti ikojade awo orin titun ti okan lara awon gbajumo olorin igbagbo nni, Ogbeni Tunde Sonola topo mon on si ‘Kennery 4 Praise’, eni to filuu Abeokuta sebugbe.
 
Kennery 4 Praise
Gege bi AWIKONKO se gbo, Ojobo Tosde, iyen ojo keta osu kejo (August 3rd) to m bo yi ni ayeye ikojade awo orin to pe ni “PERFECTION” naa yoo waye ni gbagede ileetura Praise Garden to wa ni leyin garaaji Asero ti won ti n wo moto Ibadan laago kan osan.

Ohun ti a gbo ni pe kii se ikojade awo orin yi nikan ni Kennery 4 Praise fee se lojo naa, ayeye ojo kan soso yi lo fee je oniberin, iyen 4in1, nibi to ti fee se ayeye odun keedogun to ti n forin dawon eeyan lara ya, ti yoo si tun lo afaani e fawon eeyan lami eye awoodu.

AWIKONKO tun gbo pe yoo tun se ikowojo fun ti irinse igbalode tuntun to fee ra lati mu ki ise orin to yan laayo lati maa fid awon ololufee laraya, eyi to fee ra leyin ayeye naa.

Nigba to n gbenu Kennery 4 Praise soro, Ogbeni Jeleel Ajayi topo mon on si Angel Ajayi so pe opo awon alejo olorin Fuji bii Alaaji Sefiu Alao Adekunle (Omo Oko), Igwe Remi Aluko; atawon olorin takasufe bii, Super Dee, Mr Lyno lokunrin naa ti ranse pe lati waa forin dawon alejo laraya.

Yato si awon olorin wonyii, gbajumo olorin Islam nni, Alaaji AbdulKabir Alayande, Ere Asalatu; olorin igbagbo nni, Wale Edunjobi atawon min in naa n bo lojo naa.

Angel Ajayi tun so pe Oloye Yinka Sosinde, Onarebu Musibau Alli, Oloye K. Akintunde (asinga) ati Ogbeni Akeem Lawal ni yoo je gege bi baba ojo naa, ti Pasito Arabinrin Ogunyemi, Arabinrin Olaide Nophew ati Oloye Arabinrin Tayese Ologo Omi yoo je gege bi iya ojo naa.

Lara awon ti yoo se ifilole awo orin tuntun naa ni olori ile igbimo asofin agba orileede yi tele, Dimeji Bankole, Onarebu Dotun Fasanya, Oloye Semiu Sodipo ati gbajumo olorin nni Wole Papa.

AWIKONKO gbo pe awon ilumooka sorosoro ori redio ati telifisan meji nni, Oluwasinayomi Amodu topo mon on si Agba Oro ati Van Garuba lo maa se MC lojo naa, ti won yoo si derin peeke awon alejo gege bi ise won

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI