Titi di bi a ti n
koroyin yi lowo lawon olugbe agbegbe Ojodu Berger nijoba ibile Ifo ipinle Ogun
si fi n gbe ninu iberubojo nitori ti won so pe won ko le sun ki won di oju
mejeeji mo bayii latari tawon ololufee meji kan tawon kan sekupa loru moju ojo
Eti Fraide ose to koja.
Oku won |
Gege b’AWIKONKO se
gbo, adugbo kan ti won pe ni Hassan Abiodun to wa lagbegbe Ojodu Berger ni won
lawon kan ti won ko tii le so ni pato loo seku pa Bode Ojugbele ati ololufee e,
iyen Ifedayo Bolanle, eni ti won so pe oun lo gbale sinu ile ti won ti seku
pawon mejeeji.
Bawon kan se n so pe
oro naa lowo ninu, kii soju lasan, bee lawon kan n so pe o le je awon omo
Baddoo mujemuje lo wa nidi oro naa, nitori ti won so pe se ni won fi nnkan fo
ori awon mejeeji, ko too di pe won ku patapata.
sugbon gege bi iwadii
t’AWIKONKO se, o fi ye wa pe enikan ti a ko tii moruko e titi di bi a ti n
koroyin yi, iyen eni to je ololufee Ifedayo tele lo wa nidi oro naa.
Ohun taa gbo ni pe
Bode loo ki ololufe e, Ifedayo nile nirole Ojobo Tosde, lero wipe ko lo opin
ose naa pelu e, sugbon nigba to di oru oganjo tawon mejeeji sun gege bi loko laya
la gbo pe awon kan gba oju ferese wole lati sise ibi naa.
Okan lara awon
araadugbo naa to b’AWIKONKO soro leyin isele, eni to ni ka foruko boun lasiri
so pe ko seni to le so igba tawon odaran naa wole to won, ati pe yara olopaa
kan wa nitosi ferese tawon eeyan naa gba wole, sugbon ti lo seni to gbo ariwo
lasiko ti won wole to won.
Eni naa so pe awon
mejeeji si bawon araale naa sere lale ojo Tosde naa, ti Bode si ti seleri pe
ibe loun ti maa lo opin ose naa pelu won ko too di pe onikaluku won wole loo sun,
lai mo pe olojo awon ololufe naa ti wa nitosi.
O lawon ko ti e tete
fura pe nnkan ti sele si won loru mojumo, ati pe nigba tawon ko tete ri won ki
won bo sita lo je kawon woo pe ki lo n sele, eyi lo faa ti won ni loo kan
ilekun won, sugbon ti ko seni to dahun ninu awon mejeeji.
Igba toro naa fee
koja oju ti won fi n woo, ni won ronu pe kawon loo gba oju ferese wo won,
sugbon se ni won lanu sile nigba ti won rii pe gbayawu ni ferese naa wa, ti won
ti fi obe ya gbogbo neeti to wa nibe.
Eni kan naa tun je ko
ye wa pe osu kejila odun yi lawon mejeeji n gbiyanju lati segbeyawo alarinrin
leyin tiyawo baa bimo inu e tan, nitori ti won so pe oyun to wa ninu e ti le ni
osu marun, eyi to si seese, ko bii laipe.
AWIKONKO gbo pe awon
olopaa ekun Ojodu Abiodun ni won gboku awon oloogbe mejeeji pelu aso ibora ti
won fi sun lo si mosuari osibitu jenera to niluu Sagamu fun ayewo.
Nigba to n jeri soro
naa, ati lori ibi tise iwadii won de, agbenuso fawon olopaa ipinle Ogun,
Abimbola Oyeyemi so pe aheso oro lasan lawon araadugbo n so wi pe awon omo
Baddoo lo wa nidi oro naa, nitori gege bi iwadi tawon se, ati nnkan taburo okan
lara awon oloogbe naa so je ko ye won pe ija wa laarin eni tomobinrin naa n fe
tele, ati oko afesona e to doloogbe yi.
Abimbola so pe
orisirisi ateranse to mu ifura iku dani lokunrin tawon si n sewadi e yi te
ranse si Bode to ku pelu ololufe e yi ati eni naa. O ni bo tile je nnkan to fee
sele ti sele, sugbon iyen ko so pe kawon ma sise awon lati ri odaran naa mu.
Bee lo gbawon araalu
lamoran pe ki won tubo maa nifura pupo, paapaa to ba doru nitori ko se ni to le
so nnkan to maa sele.
No comments:
Post a Comment