Iro nla gbaa ni won pa mo mi – Omodo Agba - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, July 12, 2017

Iro nla gbaa ni won pa mo mi – Omodo Agba

Ogbontarigi sorosoro ori redio nni, Alaaji Moruph Adegboyega topo mo si Omodo Agba ti so pe gbogbo aheso ti won so nipa nipa oun kii se ooto oro rara, O ni iro to jina sooto ni.

Omodo Agba
Be o ba gbagbe, laipe yi niroyin kan jade nipa egbe sorosoro FIBAN eka tipinle Ogun latari tidibo ti won di lose to koja yi, tawon kan si fesun kan Omodo Agba pe oun naa ti so fawon omo egbe naa to n seto nileese Family FM nibi to ti je okan lara awon oga agba nibe pe ti Femi Omilani ko ba ti wole gege bi alaga egbe, oun yoo le won danu.

Nigba to n bakoroyin wa soro lojo Aje Monde to koja yi, o lawon ota oun ti won ko fe ire foun lo so isokuso naa sita, nitori pe ‘as’aje ma se’ loun, nnkan toun ba so loun yoo so pe oun so, sugbon ni ti nkan ti won so pe oun so yi, iro nla pata gbaa lo je.

O so pe looto loun fe ki Omilani wole gege bi alaga FIBAN nitori pe eni to nirele, to si n bowo fagba ni, bo tile je pe oun kii se omo egbe naa nitori pe baba loun je fun opo awon omo egbe naa, sugbon oun ko gbodo tori e so nkan ti ko bojumu sita.

Okunrin naa ni aburo toun feran toun kii sii foro sabe ahon so fun un ni Adeyinka Adegbite, iyen Omo Baba Tisa, toun ko si gbadura pe ko wale lailai, sugbon sibe, bi oro idibo ba de, ko si ki oselu ma woo. O lojoojumo loun ati Omo Baba Tisa maa n soro nipa eto idibo naa ko too waye.

Bakan naa lo so pe ileese redio Family kii se toun, osise loun je nibe, ati pe oun ko lase lati da enikeni duro nileese naa, bo tile je pe oun le pase gege bi oga agba toun je, sugbon kii se bii dida won duro lori eto ti won n se.

Omodo Agba tun so pe eni to ba da loju pe oun soro naa, ko waa so ko oun loju, toun yoo si beere lowo e pe nibo loun ati e jo duro soro. O nidibo naa ti waye, o si ti koja lo, ilosiwaju egbe lo ye kawon eeyan naa maa wa, kii se lati tun da egbe naa ru.

Bee lo so pe ote ti won n se ti ko je koun fee fi taratara bawon egbe naa re e, nitori pe oun korira kawon eeyan maa je ara won lese, ki won tun maa rerin sira won, o lagba ti ko gba arinfin loun nitori pe oun naa ko figba kan ri asaaju oun fin ri.

O wa gbawon eeyan naa lomoran lati fowosowopo pelu Olufemi Omilani lati le mu egbe FIBAN eka tipinle Ogun tesiwaju, ki won si rii daju pe won n fi ife ba ara won se papo.

Lakotan, Omodo Agba gbawon agbaagba egbe naa lamoran pe ki won fowosowopo pelu Omilani nitori pe oun nigbagbo ninu e pe yoo tuko egbe naa daadaa, ti ko sii ni gboju soke wo awon to juu lo ninu egbe naa, ati pe ki won ma se foju omo kekere woo.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI