Iku ti Ladi Adebutu ko ba ku lose to koja; Omoose e lo gba ku - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, July 10, 2017

Iku ti Ladi Adebutu ko ba ku lose to koja; Omoose e lo gba ku

Orin e bami gbegba ope ni okan lara awon asoju sofin nile igbimo asofin agba nilu Abuja, Onarebu Oladipupo Adebutu, eni to je asoju ekun Ogun East nipinle Ogun n ko leyin tori koo yo lowo awon alagbapa lose to koja yi.

Gege bi iroyin to te AWIKONKO lowo se so, won ni Adebutu topo tun n pe ni LADO sese kuro lagbegbe Okeede nitosi aafin Olota tilu Ota nibi to ti lo sabewo sawon omo egbe PDP to wa leyin e ti won so pe won ti mole.

Bee o ba gbagbe, ose to koja la mu iroyin kan wa fun un yin pe awon omo egbe PDP koju ija sira won nibi ipade ti won se l’Ota nigba ti Segun Seriki jade pe oun fee jade lati dupo gomina.

Sugbon oun taa gbo ni pe ibi ipade egbe PDP ti won se l’Ogun West, iyen l’Aiyetoro ni LADO ti n bo, ko too ya ni Ota lojo naa, sugbon kii se pe o deede ya bi ko se lati gba awon omo eyin e ti won ni won tako Segun Seriki lasiko to kede ara e gege bi eni ti yoo gbegba apoti lodun 2019 ti mole sile.

AWIKONKO gbo pe ko tii ju iseju meji ti won ni LADO kuro nibe ni won lawon agbegbon kan ya de latinu oko boosi ti won gbe wa, ti won si dabon bo le, sugbon okan lara ota ibon ti won yin ba enikan ti won loo je omo eyin LADO, to si ku lesekese.

Ohun taa gbo ni pe ija oselu odun 2019 to bere lo je ki won maa le pa emi ara awon, bee la gbo pe awon olopaa ti bere igbese lati mu awon agbegbon naa nitori pe lesekese ti won gbo pe LADO ti loo lawon naa ti fese fee.

Bee la gbo pe awon agbaagba ninu egbe oselu APC to fi mo okan lara awon omo ile igbimo asofin to n soju Ado Odo Ota, Onarebu Jimoh Ojugbele naa wa nibe lakoko tisele naa waye.

AWIKONKO tun gbo pe latii ilu Aiyetoro lawon eeyan naa ti n tele Adebutu sugbon ti won so pe won ko raaye lati se nnkan ti won fee se.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI