Olori eka ikekoo ede Yoruba nileewe
awon olukoni ti Federal College of Education, Osiele nilu Abeokuta tii se
olu-ilu ipinle Ogun, Omowe Aderibigbe Morounmubo ti so pe ijoba lo n mu ifaseyin
ba ede abinibi Yoruba lorileede yi latari bi won se yo kuro ninu ilana eko
nileewe girama ati alakobere.
Omowe Morounmubo |
Omowe Aderibigbe soro yi lojo Eti
Fraide to koja yi nibi eto ayeye Ogo Oodua tawon omo Egbe Osere Ogo Oduduwa,
eka eko ede Yoruba ileewe naa se agbateru e lati fi gbe asa, ise ati ede Yoruba
laruge.
O so pe oju tijoba fi n wo ede Yoruba
to je abinibi ko dara to paapaa nile Yoruba wa nibi. O nigba kan wa to je pe
won so pe bi akekoo ko ba yege ninu ede abinibi e, ko yege ninu idanwo asekagba
nileewe girama, sugbon o se ni laanu pe won ti yo kuro, awon omo o ka Yoruba
mo, ti won o si gbo ede won mo.
Ninu oro e, o tun so pe “Nkan ti a ri
ni pe o ye kawon ijoba tu bo gbaruku ti ede abinibi wa nitori pe o ti n ku, ati
pe ti a ba wo o bayii, awon min in maa n ro pe bi omo ko ba so ede oyinbo, ko
bo sita, ko laju, won a ni ki won ma se so ede Yoruba s’omo. Elomin in o
gboyinbo, sibe a tun maa so isokuso, ti ko si ye ko ri bee. Omo to ba gbo ede
abinibi e daradara, a a rorun fun un lati ko ede elede, ti ko ni si eyi to maa
di ikokan lowo.”
O wa gboriyin fawon akekoo to sagbateru
eto naa pe ona ti won gb e e gba tun dara ju ti ateyin wa lo, o si seleri pe
odun to m bo yoo tun dara ju eleyi lo.
Bakan naa ni Arabinrin Olabowale Adams
toun je oludamoran pataki fun egbe to sagbeteru eto naa so pe egbe naa kii se
nipa imo iwe nikan bi ko se lati maa gbe asa, ise ati ede Yoruba laruge ni won
fi da a sile ni nnkan bi ogun odun seyin.
O lona ara oto ni ayeye todun yi gba
waye nitori pe iru e ko tii sele ri lati odun ti won ti n se. O so pe awon
alejo ti won fiwe pe ko kere bo tile je pe awon kan ko raaye wa, sibe won ran
asoju wa.
Obinrin naa ro ijoba ipinle Ogun lati
sagbateru eto naa, ki won si bawon fowo dowo po, ki asa, ise ati ede Yoruba ma
si le parun paapaa bo se je pe ile abinibi ti a wa yi.
Saaju akoko yi ni oludamoran pataki ati
baba isale fegbe naa, Ogbeni Omowe Adebayowa Adeniyi Adeniran so pe ipa tegbe
naa n ko nipa gbigbe asa, ise ati ede Yoruba laruge ko se e fowo ro ti seyin
nitori pe won duro gege bi opomulero asa ati ede abinibi ile Yoruba.
O wa rawo ebe sawon omo Yoruba pe ki
won ma je ki ede oyinbo pa ede abinibi run tan patapata, nitori pe Oyinbo fun
ra won ko so asa, ede ati ise nu bo tile je won tun n ko nipa asa wa.
Saaju akoko yi ni Ogbeni Adeyemo Oluwaseye
Abodunrin to soju komisana foro asa ati ise nipinle Ogun, Bashorun Muyiwa
Oladipo, so pe ipo ti eko ede Yoruba wa nipinle Ogun lasiko yi ko fi be e
moyanlori pupo, nitori pe opo awon eeyan ni ko le so ede abinibi won mo lai fi
amulumala ede sii.
O ni bijoba apapo ba le fidi e mule
gege bi won se so laipe yi pe ede abinibi ni won a maa fi ko awon omo nise
lawon ileewe kaakiri, yoo tuun dara. Bee lo so pe lati ile lo ye ki kiko ede
Yoruba ti bere.
Olori egbe osere ogo Oduduwa fodun
2016/2017, Ogbeni Sanni Yussuf Mayowa topo mo si Saani Arewa, eni to ti figba
meji je alukoro egbe naa nigba to n soro dupe lowo Olorun fun aseyori ayeye
naa, nitori pe awon ko lero pe ayeye naa le dun bo se dun yi.
Sanni Arewa ni bo tile je pe awon ko ni
eni to n ran won lowo nipa oro olowo de, eyi to je gege bi ipenija ati isoro ti
won n koju, sugbon sibe, Olorun gbakoso, tawon eeyan si gbosuba fawon.
Nigba to n so nipa awon aseyori e, o ni
idunnu subu lu ayo oun nitori pe nigba ti won maa ya noun gege bi olori egbe naa,
ko sowo kankan ninu apo egbe, to si tun je nigba ti eto ayeye yi bere, egberun
mefa ataabo (N6,500) naira lawon ri gba lati odo awon alaanu, sugbon to wa di
kayeefi fun opo awon eeyan to mo bi nkan se n lo nigba ti won ri bi ayeye naa
se lo.
O ni awoodu mewa lawon se, tawon si tun
se ounje fawon alejo, o lawon eeyan jankan-jankan tawon pe ko see ka tan bo
tile je pe gbogbo won ko ni won ri aaye wa.
Arewa tesiwaju pe lati bi odun ketala
ti won ti da egbe naa sile, saa isejoba oun lo koko se magasiini fegbe naa,
tawon si tun se iwe eri fawon igbimo egbe naa gege bi ipa ti won ko. Bee lo so
pe oun loun ji egbe naa pada dide, nitori pe opo awon eeyan ni won ro pe egbe
naa ti ku.
Okan lara awon oloye, Omidan Sowunmi
Titilayo Gbemisola, toun je amuludun egbe naa nigba to n soro rawo ebe sawon
agbaagba leka ikekoo naa pe ki won nifowosowopo pelu egbe naa nitori pe bo tile
je pe nnkan ti won n so pe ni pe abe eka eko ede Yoruba legbe naa wa, sugbon ti
itan so fun won pe ko ri bee, sibe ifowosowopo won se pataki pupo.
O ni ariyanjiyan yi lo fa a ti won fi
so pe ki egbe naa loo duro loto lati maa da nkan se, ti won ko si nii
fowosowopo pelu won. O ni aifowosowopo won ni ko tii mu kegbe naa nidagbasoke
ju bo se wa lo. Bee lo so pe ki won maa ran won lowo ni gbogbo ona.
No comments:
Post a Comment