Oro Yoruba kan lo so pe “adie kii je ifun ara won”, sugbon se loro naa da
bi eni pe oro naa ko ba tigbalode oloju taa wa yi mu mo nitori bawon omo egbe
oselu All Progressives Congress, APC eka t’Orile Ilugun nijoba ibile Odeda se koju
ija si ara won l’Ojoru Wesde to koja yi.
Mofoluke |
Ibeere tawon eeyan to gbo nipa isele naa ni pe ‘ki loo fa ija’ nitori bi
won tun se so pe nise lawon olopaa ti won ni ki won wa daabo bo awon eeyan tun se
koju ibon sawon araalu nigba toro naa di bolo o yago lona.
AWIKONKO gbo pe asiko tegbe oselu naa se abewo kan ti won pe ni Mid-Term
Assessment Tour sawon igberiko kaakiri ipinle Ogun ni wahala naa be sile lakoko
ti ayeye naa n dun mo won.
Won ni bi odun 2019 se n sunmo etile lawon eeyan naa ti bere sii gbogun ti ara won lati da egbe naa si meji, konikaluku si duro laaye ara e lati ni omoleyin ti e.
Enikan tisele naa soju e so pe kii se pe won deedee da wahala naa sile bi
ko se pe won fee pa alaga ijoba ibile idagbasoke Orile-Ilugun, Arabinrin
Mofoluke Sowemimo gege bi won se so pe obinrin naa ti n dari won lati igba
Otunba Gbenga Daniel.
Won ni Onarebu Adebayo Olashehu to je oludamoran fun gomina ipinle Ogun, iyen
Consultant to the governor on IGR, eni
to ti n se ipolongo lati dupo lati soju awon eeyan ekun naa nileegbimo asofin
agba nilu Abuja lodun 2019 lo sagbateru awon janduku to da ayeye abewo naa ru.
Bee l’AWIKONKO gbo pe eeyan to wa nibe lojo naa le ni egberun meji lati
ye alaga won si fawon ise akanse to se sibe, sugbon to je pe asiko ti ayeye naa
n dun lawon janduku ti won ni Onarebu Olashehu ko wa sibe ti won ko ju aadota
lo dide lati daa ru.
Enikan naa tun t’AWIKONKO lolobo pe akowe ijoba idagbasoke Orile-Ilugun,
Ogbeni Jelili Adeogun naa wa lara awon to sagbateru bi wahala naa se waye
nitori ti won so pe nise lo deede gbabodi fun alaga won to wa labe e.
Imura ti won ni Onarebu Olashehu ati Jelili Adeogun ti se lo je ki won ko
awon olopaa ti won n lo lati loo gba owo ori lowo awon araalu dani lo lati loo
fibon won tu won ka.
Lati fidi oro yi mule lo je ki AWIKONKO wa alaga yi, Arabinrin Mofoluke
lo si ofiisi e lose to koja lati foro waa lenu wo, to si so pe bi kii ba a se
pe oore ofe Olorun wa lara oun ni, o seese koun ti ku nitori pe oun gan an ni
won doju ko lati pa.
O nibi ti won ti n le oun pelu ese kan aabo toun ni ni komu (bra) oun ti ja sonu, toun ko si lee so
ibi ti bata meji ese oun gba. O lohun ko ni lero pe awon eeyan toun ko lo inu
meji peluu won le pe apejo ote le oun lori.
Arabinrin Mofoluke to tun je diakoni (Deaconess)
so pe bi ala loro naa si n ri loju ohun ati pe wahala toun n ba pade lojo naa
ti da aisan soun lara, nitori pe se ni won tun beresiya oun ja, ti won gba bata
lese oun, sugbon to je pe Olorun lo koun yo lowo won.
Lati fidi oro naa mule siwaju sii lati ba Onarebu Olashehu ati Ogbeni
Jelili Adeogun ti won fesun kan soro, gbogbo igbese ti a gbe lo ja si pabo titi
digba ti a fi sakojopo iroyin yi tan.
No comments:
Post a Comment