Igbakeji oga agba ajo Fijilante nipinle Ogun ti ku o - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, July 14, 2017

Igbakeji oga agba ajo Fijilante nipinle Ogun ti ku o

Beeyan ba wa nibi ti awon omoleyin Oloogbe Bisiriyu Olufemi to je igbakeji oga agba fun ajo eso ojulalakanfiisori, Vigilante Group of Nigeria, eka tipinle Ogun ti se eto ibanikedun ti won pe ni Ale Fitila, Candle Night fun oloogbe naa l’Ojoru Wesde to koja yii, yoo mo pe ko wu won ko ku lasiko yi.


Oloogbe Bisiriyu
Gege bi AWIKONKO se rii gbo, Oloogbe Bisiriyu ku lojo Eti Fraide ose to koja leni odun mejilelaadorin (72years) nileewosan Ogun State University Teaching Hospital, OSUTH to wa niluu Sagamu latari aisan ojo ogbo ti won loo se e.

Aisan naa ni won so pe o ti le ni osu meloo kan to ti wa lenu e, to je pe se lo n fojoojumo lo sileewosan lati loo gba itoju, sugbon nigba toro naa fee yiwo ni won so pe awon dokita gba a nimoran pe ko loo ojo meloo kan lodo won, lati le je ki won raaye toju e daadaa, ko si gbadun.

Omi teyin wogbin lenu nigba tolojo de lati mu emi baba agba naa loo, nitori ti won so pe Oloogbe Bisiriyu ti figba kan sise pelu ajo eso ologun, Nigerian Army nibi to ti gba oye Major ko too di pe o feyinti.

Leyin ifeyinti e lawon kan ti won mo ipa to ko lakoko to wa lenu ise ologun pe e pe ko wa, ki won le tun ronu ona min in lati fi ran orileede yi lowo nipa eto aabo to peye laarin ilu.

Oloye Bisiriyu gege bi iroyin to te AWIKONKO lowo je ko ye pe o peluu awon ti won jo da ajo Fijilante VGN sile lodun 1999, to si sa gbogbo agbara e lati je ki ajo naa fese mule kaakiri orileede yii.

Biroyin iku baba naa se kan sawon ti won jo n sise ninu ajo Fijilante la gbo pe won bere sii lo bawon ebi baba naa kedun nile e, eyi gan an lo faa ti won fi ya Ojoru Wesde to koja yi soto lati fi sayeye ikeyin ti ale fitila fun oloogbe Bisiriyu, bo tile je pe ojo keji ti won ni baba naa ku ni won ti sinku e nilana Musulumi.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI