Goliath ni Gomina Amosun je nipinle Ogun nitori pe ise asinwin lo n se kaakiri – Harrison - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, July 10, 2017

Goliath ni Gomina Amosun je nipinle Ogun nitori pe ise asinwin lo n se kaakiri – Harrison

AWIKONKO: Oruko yin lekun rere ati ipo ti e di mu?
HARRISON: Oruko mi Omoba Adeyemi Harrison ti mo je asoju-sofin to n soju ekun Ogun Waterside nile igbimo asofinn ipinle Ogun.

Onarebu Harrison
AWIKONKO: Ti a ba ni ka woo, bii ijoba ibile meloo lo wa lodo yin ti e n soju fun?
HARRISON: Woodu mewaa lo wa lodo wa.

AWIKONKO: Odun keloo re ti e ti wa gege bi asoju-sofin?
HARRISON: Ti a ba ni ka woo, o ti to odun mefa ati osu kan.

AWIKONKO: Nje e ti e le menuba awon nkan gboogi ti e le so pe o je aseyori yin lati odun mefa naa seyin?
HARRISON: Se e mo pe asofin la wa, owo osu la si n gba, sugbon sibe ninu owo osu wa ati awon owo gba mabinu ti a gba, a n se nnkan ti agbara wa ka, tori pe gege bi ofin, ko ye ki asofin ko maa se ise akanse, sugbon gege bi ero okan awon eeyan wa, won ti ro pe eni to ba ti loo soju won, a fi ki won dawo le ise akanse. Opo ninu won lo gbagbo pe bi won ba ti dele igbimo asofin, owo ni won loo n pin. Won ko roo pe owo osu nikan laa n gba ati awon owo ijokoo. Eekan soso la si n gba owo ijokoo naa, ohun ni won n pe ni alawansi.

Nigba ti mo koko de, mo se nnkan ti won n pe ni bursary fawon omoleewe giga fasiiti, to je pe egberun mewa naira fun awon to to aadoje (150) eeyan. Leyin yen, a se borehole to to marundinlogbon. A tun awon ileewe kan se. Ijoba tun ba wa ko ile kan loruko wa. A gbe okada fawon odo to nilo e latari aisi ise ti won n pa ti ko sileese ti won ti maa sise, nitori pe eeyan ko le fi won sile ki won loo jale, eni to ba ni okada to fi n sise lojumo, owo a maa wole fun un, o le fi bo ebi e. bo tile je pe ogorun kan (100) la fee fi bere, sugbon nigba taa bere ti a ri bawon eeyan se po, lo je ka soo di 180. Nigba to ya ti a rii pe owo okada naa lo soke, a bere sii fun awon ti a ti seleri fun lowo, pe agbara wa o ka mo, a si fun won lowo, eni to gba N120,000, eni to gba N140,000 wa ti won loo fowo kun lapo ara won.

Nigba kan ti omi ya wo awon ile kan, won rawo ebe sijoba, sugbon nigba tijoba ko dide iranlowo, emi ni mo dide ti mo loo pin foonu, sitofu idana atawon nnkan min in fun won, ki won ma di alaileeyan. Bee naa la se fawon alaboyun ti won ri eni to le ran won lowo. Bee lawon toko won ko rowo ra eru omo la ran lowo.

AWIKONKO: Nje e ti e le fowo e soya pe awon eeyan yin ti e n soju fun je mudunmudun ijoba ipinle Ogun?
HARRISON: A o gbodo paro ttan ara wa je, awon eeyan mi o je anfaani kankan lati odo ijoba ipinle Ogun. Won jere nigba isejoba Otunba Gbenga Daniel, beee naa ni won jere nigba ti Baba Olusegun Osoba. Lakoko OGD ni won gbe ileewe giga wa sibe. Lakoko Osoba ni won se ina monamona fun wa. Nigba yen Tayo Ajayi toun wa ninu egbe oselu PDP lo wa gege bi alaga ijoba ibile. Aimoye ona ti OGD se fun wa nigba yen. O tun ko awon ile agbebi. Kanselo lemi naa se nigba yen to je pe OGD maa n fun wa nise agbegbe . ninu awon ise ti won gbe le mi lowo nigba yen ni ileewe kan to ti wo tan, emi ni mo loo ko pada sibe.

Baa se pari ni won ti bu owo lu lesekese ti won si bere sii lo dasiko yi. Sugbon o se ni laanu pe awa ti a je omo ileegbimo asofin, o ye ka maa gba owo ise akanse losu metameta sugbon ti a o gba nkankan latigba ti a ti de. Gbogbo e ni won ko papo ti won ni won fi n se ijoba, ti won n se afara oloke kaakiri. Mo le fi gbogbo enu soo pe Water Side ko je mudunmudun ijoba Amosun kankan bi mo se n soro yi, sugbon mi o le so to ba di ola ti ile ba mo. A ti soro ninu yara, ninu yara igbalejo, ni ofiisi, lori redio, bakan naa lo ri, ko si ayipada. A tun ti rii pe won fee lo se ona meje kan, bo tile je pe won ko sese maa paro fun wa pe won fee se ona meje, o ti pe ti won ti n so o. mo mo pe Olorun a mu alaanu wa wa laipe laijina.

Awon agbalagba lo maa n powe kan pe ‘kekeeke alaboyun ko ni koja osu mesan an’, ti a ba ri eni to se gomina, yala o se daadaa tabi idakeji, ko le koja odun mejo, nitori pe ko le koja ofin. To ba se tan, dandan ni ko di gomina ana, elomin in a tun wa. Adura wa ni Water side ni pe eni to ba n bo, ki Olorun je ko je alaanu wa bii ti Daniel, Osoba, Olabisi Onabanjo, ko ma je eeyan bi Amosun nitori pe ota Waterside ni. E ba wa beere lowo Amosun pe ki ni nnkan to ti se si Waterside ati ese ti Waterside ti se e, tori pe mi o mo. Gbogbo eto wa lo fi n dun wa ni Waterside. Gbogbo awon Oba lo n fun ni moto, ko fun Oba kankan ni Waterside ni moto. Waterside ko jere lara ijoba Amosun. Ere ti a je nijoba Amosun ni pe lakoko Easter, Ileya ati Disemba, a maa pin raisi pelu eran meta meta si woodu kookan.

AWIKONKO: Ipo wo lawon oju ona to wole si Waterside wa lasiko yi nitori pe lakoko ipolongo idibo loduun 2015 ni adagun omi fi wa lawon oju ona naa?
HARRISON: Odun 2015 ti e n so yen ti pe e, bi e ba debe bayii, ee ri pe o ti buru ju yen lo bayii, ko si atunse kankan si won. eleyi to tun wa ya wa lenu ni pe bi won ba fee wa se nnkan towo e to egberun lona oodunrun (N300,000 si N500,000) naira, igba ti adari wa ba ku lo maa wa se e. Baba kan ti won n pe ni Baba Ademoye, igba ti baba yen ku lo ba wa tun ona naa se die nigba ti won fee sinku kan, ti won si gbee sita pe oun ti se ona fun wa. Nnkan to n so fun wa ni pe ka maa pa awon asiwaju wa lati fi gba ona. Nitori pe latigba ti a ti n bee lo je pe ko se nkankan ayafi tawon adari wa ba ku lo maa too se ayederu sawon ibi to baje. Ko si anfaani kankan ti a je nijoba ibile mi bo tile je pe APC kan naa la jo jee, ko si le le mi kuro ninu egbe APC, to ba si so pe dandan ki n kuro, aimoye egbe oselu min in nitori pe egbe oselu PDP ni mo gba wo APC.

AWIKONKO: Ki lo faa ti e fi kuro ninu egbe oselu PDP bo sinu egbe oselu APC ati pe se e ri nkan ti e ni lokan lati ri ninu egbe oselu APC le ri nigba tee darapo?
HARRISON: E se pupo, nigba ti a maa pade nibi nitori pe PDP ni mi tawon kan bii Buruji ati daniel ti bere sii ja, ti Obasanjo naa ti duro loto. Agidi ni mo fi kuro ti mo fi woe gbe oselu APC nipa ife Olugbala. Igba ti a de ti a ri baba onifila, ero okan wa ni pe bo se n se l’Abeokuta naa lo maa se kaakiri pelu gbogbo ileri to se fun wa. Odun merin akoko la fi duro ti ko yoju si wa depodepo pe won maa wa se nnkan, igba to ya o tun so pe boun ba wole eleekeji, eleekeji lo ti fee pari bayii, ti a o ri eyin aso e. Ati pe wahala taa fi sile ninu egbe oselu PDP ko tii kase nile dasiko yi. Airi atunse ara won yi lo n mu isekuse ti won se l’Ogun yi wa, ti won ba ri atunse ara won, jatijati ti won n se yi ko le sele. Mo gbadura pe Olorun a ba wa too.

AWIKONKO: Nje oro naa ko dabio abamo fun un yin pe e darapo mo egbe oselu APC to je pe gbogbo eto yin ni won fi n dun yin?
HARRISON: Kii se emi nikan ni mo kabamo yi, gbogbo awon omo Waterside ni won kabamo papo nitori pe gbogbo won ni won fowo si Amosun nigba naa. Gbogbo awon to ba ti je omo Waterside ni won kabamo pe awon segbe APC, won tele Amosun. Abamo nla lo je.

AWIKONKO: Ariwo tawon kan pa nigba kan ni ina monamona n je won niya, ti Senato Dapo Abiodun si gbe ero amunawa tiransifoma wa, bawo ni oro ina bayii?
HARRISON: Ko sigba ti Senato Abiodun gbe ero amunawa wa fun wa, o tun ina to ba je se ni, o si ra awon opo ina min in dipo awon to wo, bee lo se waya. Latigba ti Osoba ati Daniel ti kuro, a o ri eni to le bojuto oro ina naa mo, iya n je wa lori ina yen gan, sugbon nigba ti Dapo Abiodun de, lo se gbogbo fun wa, sugbon sibe, a si n ri ina die-die lo lekookan. Tele fun odun marun un, a le ma foju kan ina, sugbon ni bayii, a ti n rina bi eemerin losu bayii, aarin wakati meji si merin si ni. Iyen nikan ni a le so pe a jere egbe oselu APC nitori ina  ti Dapo Abiodun se fun wa.

AWIKONKO: Se kii se pe boya ija oselu wa laarin eyin ati Gomina Amosun?
HARRISON: Olorun ko je, ko si nkan to jo bee. Amo sa, ija oselu tun wa bayii nitori pe ko se nkan kan fawon eeyan mi. se mo fee gbe apoti Gomina? Mi o gbe apoti Gomina taa ba so pe boya o le je anfaani lati maa ba ja. Mi o tii gbo ri kaakiri agbaye pe eeyan ko ileewe akanse (constituency school), ko si gbawon tisa sibe. Awon ileewe to ko ni ko se nkankan sibe. Alagbara ni, Oluwa a si ba wa parowa fun Goliath. Goliath ni Gomina Amosun je, emi ni Dafidi.

AWIKONKO: Ohun taa gbo tele ni pe Dapo Abiodun le n tele tele, o tun ya won ni e ti wa leyin Yayi, bee lawon kan tun so pe odo Ladi le wa, ewo gan an lo je ooto nibe?
HARRISON: Oro temi ko leleyi o. E mo kini kan ti won n pe ni Alagemo?, ko seni to le mo irin Alagemo nitori pe to ba debi ti funfun wa, o maa ba lara mu, to ba debi ti aawo ewe wa, bee naa lo maa ba lara mu. Bakan naa to ba debi ti dudu wa, aa tun ba lara mu. Eda eeyan kan ko le mo bi mo se maa se ojo ola mi, o n tan ara e je ni. Ti asiko ba to, won a mo ibi ti mo wa.

AWIKONKO: Ki le wa fe kawon eeyan yin ni Waterside se bayii pelu bi e se so pe won n fi eto yin dun yin?
HARRISON: Ti asiko ba to lati je ki won mo nnkan to ye ki won se, won a gbo. Awa la nile wa. Waterside ni won ti bi mi, nibe naa ni mo ti bere sii rin, omi e ni mo mu dagba, ibe ni mo ti lo sile eko alakobere. Waterside ni mo ti feyawo mi, ibe ni mo kole si. Gbogbo igbesi aye mi, Waterside ni mo ti se e, yato si pe mo sere jade ki n si pada sibe. Bi won se fee gbe ase won kuro nilu Abeokuta lo si Waterside, won a so fun mi tasiko ba to.

AWIKONKO: Awon araalu gba pe awon asofin lo maa n daba, ti e si maa n se awon akanse ise, sugbon ni saa keji yi, ko si nkan to jo be, ati pe ko sise kan ti e se ni pato. Won ni se le maa ru owo (hand) sapo ni. Ki loo fa?
HARRISON: E se o. se e ri ijoba eleyi, ijoba ka maa se biriji ni, kii se ijoba kawon eeyan je, nitori pe nnkan temi ri ninu ijoba ti a ba wo daadaa, awon ise asinwi lo po ju nipinle Ogun ti won n se lowolowo bayii. Fun awon to ba woo, won a mo pe ise asinwin ni. Nnkan ti mo n so yi, ti won ba gbo ki won wa pa mi nitori pe nibi tojo ori mi de yii, gege bi omodun mokandinlaadota (59years), ti m ba ku, awon ebi mi a pa maalu, ti won o ba ti e ri oku mi gbe, dandan ni ki won pa maalu.

Ti omo Naijiria kan ba wa, tojo ori e ti to ogbon, to si n beru eeyan kan, oloriburuku ni nitori pe eto ilu yen lo fee fi dun awon araalu. Emi o beru enikeni, paapaa bo je aare orileede ni, nnkan to ba se ni mo maa so. Awon kan n gbe bombu, awon ti o to mi lo n se Boko Haram, ti won n di bombu mora, ti won lo n yin ninu oja kaakiri, aye o tori e pare. Eto won ni won n ja fun, digba ti won ba too fun won leto won. Baba Awolowo naa ti so o ko too ku pe to ba to akoko, onikaluku maa dide lati ja feto e, asiko naa si ti fee to bayii. Se Abeokuta je ilu to je pe inu ira (Swampy) ni, to fi di pe a n fi owo se biriji kiri? Se won n fi gbayi laarin ilu ni? Ti e ba de agbegbe Akute, awon biriji kan wa nibe to nitunmo, to je pe awon eeyan ko ribi soda lori omi yen, iru awon nkan ti a n so niyen.

E wo ni biriji were laarin kaakiri? Se dandan ni kawa naa maa fara we awon ara Eko pe won n se biriji ni? Ti e ba wo ona NNPC si Abiola way, se bawon eeyan ba n rin in lai si biriji, se won o ni gbadun e ni? Owo ti won fi se awon biriji Abeokuta nikan yi, o ti to llati pari gbogbo awon off-street to wa l’Ogun, ti enikan ko si ni so pe ijoba ko se nkankan, gbogbo agbegbe ni won maa mu owo de. Ka maa fi bilionu meta si merin se biriji kan soso silu kan soso, ko bojumu rara. Sugbon tori won ro pe awon omo ipinle Ogun, araoko ni won, won o laju, ona lati fi ji owo ni nitori pe awon ise ti won n se, awon ise teeyan ko le so pe iye bayii lo pari e ni won n se. Awon ise ti won maa na bilionu kan naira si, ti won maa pe ni bilionu mewaa.

Ijoba ole nijoba ti Amosun n se lowo yi. Ile igbimo asofin gan an ko le dahun pe iye bayii ni won na sawon ise yi. E loo wo awon ileewe igbalode ti won ni won ko, won ko tii lo di akoko yi nitori pe won o n ro won loju lati san owo osu awon tisa ni ko je ki won ti bere e. To ba ti wa fee ku osu mefa ki won lo, won a wa sese si awon ileewe igbalode naa lati le je ki orun wo ijoba to n bo, ibere 419 ni. Odun keta si kerin re e ti won ti pari e, ti won o si, sugbon sibe won n si biriji ti o gba inawo. Ti e ba wo biriji ti won n se lowo si NNPC, o seese ki won si nigba Ileya laity pari e. won o se si awon ileewe igbalode yi bee, ki won gbawon eeyan to to egberun marun un ti won a maa san owo fun? Won n wo ile kiri. Ijoba ko leleyi. Odun merin ijoba yi ko nitumo sawon omo ipinle Ogun, adanu lasan lo je. Ko si nkan to da lati odo ijoba yi.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI