Femi Adebowale lu iyawo e pa nitori egberun mewaa naira - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, July 25, 2017

Femi Adebowale lu iyawo e pa nitori egberun mewaa naira

Ika abamo ni Femi Adebowale to lu iyawo pa nitori egberun mewaa lojo Aje Monde to koja yi mu bo enu lago olopaa leyin to wo te, tawon olopaa si so pe a fi ko foju bale ejo.
 
Ojule keedogun, adugbo Campbell, Agbado nilu Ifo la gbo pe isele naa ti waye, nigba ti won so pe se ni lokunrin ti won loo sese pe ogoji odun naa ko igbaju igbamu bo Kuburat, toun je omodun metadinlogoji, ko too di pe o dake mon on lowo.

Ohun taa gbo ni pe lojo tisele buruku naa waye, won ni Kuburat lo so fun oko e Femi pe ko foun lowo, nitori pe aburo oun, Shakiru fee sekomojade, sugbon ti ko sowo lowo oun lati sebi egbon fun un.

Lesekese ni won ni Femi so fun Kuburat pe ko sowo toun fee fun, ati pe ki lo de ti ko loo bawon to n yan lale lati gba owo lowo won, to fi je pe owo oun lo ti fee gbowo to fee na nibi ikomojade aburo e.

Oro yi ni won loo bi Shakirat ninu to fi bere sii so orisirisi oro, ko too di pe Femi fibinu ko egberun mewaa naira sile pe ko loo fi se nkan to ba fee se, sugbon kakaki Kuburat dupe lowo oko e, se loo so pe owo naa ko to oun, afi koun gba sii.

Lara awon to gbe oro naa s’AWIKONKO leti so pe se ni Kuburat lo aso mo Femi lorun pe boun ko baa gba owo sii, oun ko nii fi sile, eyi lo faa toro naa fi gbodi lara Femi, to si bere sii luu.

Awon ti won jo n gbe ni won ni won gbo ariwo awon mejeeji lati loo yanju oro naa fun won, sugbon iyalenu lo je nigba ti won fi maa wole to won, ti won ba Kuburat nileele, to n pofolo.

Ibeere ti won beere lowo Femi ni pe ki loo sele, to si so fun won pe wahala e ti poju, ati pe o n fe enikan tawon jo n gbe ladugbo, toun si ti kawon mo laimoye igba.

Gbogbo bi won se n ro omi le Kuburat lori, pabo lo n jasi, eyi lo faa ti won fi sare gbee lo si ileewosan kan to sunmo won, sugbon ki won too de be, oro naa yiwo mo won lowo, Kuburat ti ku.

Lesekese ni won lawon araale naa ti ranse si Shakiru Alao to je aburo Kuburat, eni ti won loo fe sekomo omo tuntun to bi, bo se gboro naa lo ti gbera lati loo mo nnkan to n sele. Nigba to maa de be, oku egbon e lo ba.

Ibinu ni won ni Shakiru fi gba tesan olopaa lo lati loo foro naa to won leti, ko too di pe DPO Agbado, Ogbeni Sunday Omonijo lewaju awon olopaa to loo mu Femi. Pakopako ni won ni Femi n wo bi maalu to ri obe. Lesekese la gbo pe won ti gboku Kuburat lo si motuari jenera to wa nilu Ifo fun ayewo kan ti won pe ni autopsy.

Igbe ebe ni won ni Femi mubonu pe kawon olopaa dariji oun nitori pe oun ko mon on mo luu pa, ati pe ise esu. O loun ko le so emi to gbe oun wo lojo naa, nitori pe oun kii fee ba ja.

Nigba to n so boro naa se je, Femi so pe “O wa bami pe aburo oun fee sekomo, ko sowo lowo oun, emi naa so fun pe mi o lowo lowo, ko loo mo bo se maa ri owo. Mo fun un ni egberun mewaa naira, se loo so pe ko le se nnkan toun fee fi se, kaka ko so pe mo se, ko dupe.

“Nigba ti wahala e po, mo sun un pe ko loo ba okunrin to n fe nitosi ile wa. O so pe ko si nkan to kan mi. Idi ti mi o fi fun lowo sii ni pe agbere to n se ko te mi lorun. Ojoojumo lawon eeyan n soro e fun mi pe o n sagbere. Mo kan gba leti ni, lo ba subu, mi o mo pe bo se maa ri ni yen. Mo fe kawon omo Naijria dariji mi, ki won ba mi be awon olopaa atawon ebi iyawo mi.”

Komisana olopaa ipinle Ogun, Ahmed Iliyasu nigba to n soro so pe boun se ti gboro naa loun ti pase pe kawon olopaa toro naa kan tesiwaju  lori oro naa, ki won si rii daju pe won foju Femi bale ejo.

Ohun taa gbo bayii ni pe ose yi gan an lawon olopaa yoo foju Femi bale ejo, leyin ti awon dokita ba ti pari ayewo autopsy ti won fee se.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI