Eyi ni bi Wale Adewumi se di alaga eka asojukoroyin l’Abeokuta - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, July 19, 2017

Eyi ni bi Wale Adewumi se di alaga eka asojukoroyin l’Abeokuta

Idunnu nla lo subu lu ayo repete lonii laarin awon omo egbe eka asojukorin ti a mo si Correspondent Chapel to wa ni Isabo, Abeokuta ipinle Ogun nigba ti won kede Ogbeni Wale Adewumi gege bi alaga tuntun fegbe naa.

Lakoko to n gba ipo naa lowo alaga egbe NUJ, Sokunbi
Gege bi AWIKONKO se gbo, eto idibo naa bere ni nnkan bi aago mokanla aaro oni tii se Wesde ni won so pe ko pe rara ti won fi pari e nitori ti won so pe eto idibo naa lo bo se ye ko lo.

Ohun ti a gbo gege bi nnkan to faa ti idibo naa ko fi gbawon lakoko ni bi won se so pe ko si alatako laarin awon to gbapoti lati du ipo ninu egbe naa, bo tile je pe won lawon kan ti won gba foomu ti fiwe ranse ni ale ana Tusde pe awon ko se mo.

Awon mefa lo gba foomu gege bi AWIKONKO se rii gbo sugbon tawon meji so pe awon ko nife sii lati tesiwaju mo ninu idibo naa nitori awon idi kan ti ko ranse sawon igbimo to dari eto idibo naa.

Ogbeni Sulaimon Fasasi ti ileese iwe iroyin Nigerian Pilot toun ti gba foomu lati di alaga ati Ogbeni Rasaq Ayinla ti ileese iwe iroyin Business Day la gbo pe won fiwe ranse pe awon ko nife si ipo naa mo.

Eyi lo fa ti idibo to gbe Ogbeni Wale Adewumi ti ileese iwe iroyin Top Celebrities, alaga; Ogbeni Gbenga Adeboye ti ileese iwe iroyin Leadership, akowe; Ogbeni James Ogunnaike tileese iwe iroyin Business Day, akowe owo ati Ogbeni Abiodun Lawal tileese iwe iroyin News Agency of Nigeria (NAN), akapo wole fi ya ni kankan.

Lesekese ni won ti se ibura fawon eeyan naa pe ki ise won bere lai fi akoko sofo rara, nitori pe ko tun si nnkan ti won duro se mo, to le fee je ki won mu ojo miran lati sebura fun won.

Nigba to n soro, alaga to gbe ipo naa sile, Ogbeni Kunle Olayeni tileese iwe iroyin New Telegraph so pe ojo naa re bi ana toun toun gba ipo naa leyin idibo ti won se lodun meta seyin.

Okunrin naa loun dupe gidigidi lowo awon omo egbe naa fun adurotii won ati igbaruku ti won lakoko toun fi je alaga egbe naa, ati bi won se fowosowopo pelu oun ti won ko je ki oju ti oun.

Olayeni so pe oun ko le menuba awon aseyori oun gege bi alaga tan, sugbon nigba toun maa gba opa ase lodun 2014, ko si owo kankan ninu apo egbe naa, sugbon ni bayii, egberun lona igba naira loun fi sile.

Awon oloye tuntun pelu Ogbeni Wole Sokunbi
O soro lori bi ero ayelujara intaneeti se ti n sakoba fun ise iroyin ti won yan laayo, eyi to fa tawon eeyan ko fi foju to dara wo awon akoroyin mo bo tile je pe awon to mo riri ise won n gbosuba kare fun won.

O gba asojukoroyin lamoran pe ki won maa koju mo ise ti won ba loo se ni ta, ki won ma reti pe ki eni to pe won sibi eto kan maa fun won ni apo iwe ti won n pe ni Brown Envelop ki won too lo.

Bakan naa lo gbawon ti won sese dibo yan lamoran pe ki won tuko egbe naa daadaa, ki won si je ki ife tubo jinle laarin si awon omo egbe asojukoroyin. O wa muu dawon loju pe oun yoo sa gbogbo ipa oun lati fowosowopo pelu won, ki won si se aseyori nla.

Saaju akoko yi ni alaga egbe asojukoroyin nipinle Ogun, Komureedi Wole Sokunbi so pe iyalenu lo je foun nigba ti won so pe egberun lona igba naira lowo tawon to sese gbejoba sile fi sile ninu apo egbe naa, nitori pe iru e ko tii sele ri.

Sokunbi ni ko si owo to to bee ninu apo egbe to tun je baba fun won, o ni ise gidigidi ni won se, ati pe iwuri nlan lo je foun, toun si gbodo gbosuba kare fun won gege bi ise ti won se.

O wa ro awon omo egbe naa pe ki won tubo je ki ife ooto tubo jinle si laarin won, nigba to n mu dawon loju pe oun setan lati ran won lowo nibi ti won ba fe iranlowo oun.

Bee lo gbawon oloye tuntun naa lamoran pe ki won ma se ri ipo naa gege bii pe won ti debi ti won fee de, sugbon ki won rii gege bi eni to fee sin awon eeyan won.

Saaju akoko yi naa ni alaga tele, Ogbeni Kunle Olayeni fi iwe sowedowo ranse si idile okan lara won to doloogbe lodun to koja, Oloogbe Abiodun Onafuye to je asojukoroyin The News/PM News.

O so pe ipa ti Onafuye ko ninu egbe naa lakoko to wa laye ko le je kawon gbagbe e, ati pe iku e dun won pupo. O ni o ye kawon ti ta ebi naa lore tipe, sugbon awon n duro de asiko ti yoo je ki nkan naa joju.

Awon oloye tuntun pelu awon asojukoroyin
Alaga tuntun, Ogbeni Adewunmi, eni to tun je akowe to sese gbe ipo sile, nigba toun naa n soro, dupe lowo awon omo egbe naa  fun bi won se gbaruku ti oun lakoko toun je akowe agbe naa, pelu ifowosowopo won lasiko ti won bere eto idibo naa titi to fi pari.

O ni ife egbe naa to je oun lo je koun gbegba apoti fun ipo naa, toun si nigbagbo pe iwa oun lo gbe oun wole, kii se nkan min in, ati pe. O loun yoo sa gbogbo agbara oun lati mu idagbasoke, ife ati alaafia joba laarin awon omo egbe naa.

Adewunmi so pe bo tile je pe ko too di akoko naa loun ti n gbe igbese lati je ki isokan joba ninu egbe naa, toun yoo si ri daju pe ko awon pa ina eleyameya to wa laarin awon omo egbe naa.

Lara awon agbaagba to wa nibe lojo naa ni Ogbeni Idowu Oyindamola, Hallmark; Ogbeni Femi Oyeweso, National Mirror; Ogbeni Wunmi Akinola, Vanguard; Ogbeni Olu Osikoya, National Daily; Ogbeni Dayo Rufai, Encomiun; Musilimu Aremu, New Nigerian; Ogbeni Johnson Onifade, First Weekly Magazine; Ogbeni Niyi Ogungbola, New Nigerian; Ogbeni Soji Amosun, National Orientation Agency atawon min in.

Awon igbimo eleto idibo naa ni Ogbeni Laide Raheem, The Sun; Ogbeni Johnson Akinpelu, Alaroye; Abiodun Taiwo, Daily Times ati Bunmi Mustapha, City People.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI