Egbe sorosoro FIBAN se idanilekoo aawe Ramadan akoko - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, July 3, 2017

Egbe sorosoro FIBAN se idanilekoo aawe Ramadan akoko

Titi di bi a ti n koroyin yi lawon eeyan atawon ololufe egbe sorosoro FIBAN eka tipinle Ogun si fi n royin idanilekoo eyi ti won fi pari aawe Ramadan odun yi ti won se lojo Abameta to koja ninu gbongan awon oniroyin to wa ni Oke-Ilewo nilu Abeokuta.

Aare FIBAN
Ara oto ni idanilekoo naa gba waye ati pe akoko iru e lo je nitori awon eeyan pataki to wa nibe lojo naa bii Oloye Alani Bankole to je baba isale (Grand Patron) egbe naa to je alaga pataki ojo naa; Alaaji Sheik Abdul Lateef Ademoye Ya Satar to foro Olorun dawon eeyan lekoo; Alaaji Sheik Abdul Kabir Oyegunle.
Nibe naa ni awon gbajumo olorin Islam bii Alaaji Bukola Alayande, Ere Asalatu; Hajia Jemilat Opeyemi Alagbe ti forin Islam dawon eeyan lara ya.

Nigba to n soro Alaga ojo naa, Alaaji Alani Bankole lo ti gboriyin fun ipa ti egbe naa n ko lawujo paapaa lorileede Naijiria, o so pe ko si egbe to dabi egbe naa tori pe awon ni won mu olaju bawon eeyan lawujo. Bee lo gbosuba kare fun Alaga eto naa, Ogbeni Gbenga Oladunni, Imalian Boy fun akitiyan e pelu ona ti won fi gbe eto naa kale.

Bee lo so pe  oriire meji tegbe naa se laarin odun kan, ko tii si egbe min in lorileede Naijiria to seru e ri, nitori pe Abeokuta ni won ti yan Aare egbe naa, bee lo tun je pe ninu awon omo egbe naa ni won tun ti mu akowe ijoba ibile ni Ado Odo Ota.

O rawo ebe sawon eeyan pe ki won maa fi ife ba ara won lo, ati pe ife ni kan lo je ki orileede Naijiria gun oke agba. Bakan naa lo ni bi a ko baa ti yo oro eleyemeya kuro ninu oro wa lorileede yi, ko le si itesiwaju.

Saaju akoko yi ni Aare egbe naa lorileede Naijiria, Ogbeni Desmond Abiodun Nwachukwu ti so pe orileede Naijiria n fe adura nitori pe bi ako ba tete dide fimo sokan lati gbadura fun orileede yi, o see se ki Naijiria tuka.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI