Bi kii ba se pe awon olopaa digbojula
FSARS ti won wa nibi idibo egbe awon sorosoro FIBAN tipinle Ogun to waye lojobo
Tosde ose to koja ko si ni kawon omo egbe naa gbara won lese daadaa sibe pe won
wa nibe naa, won foju won ri mabo.
Lakoko wahala naa |
Gege bi AWIKONKO se gbo, ibo egbe naa
to waye ofiifi egbe won to wa ni Nawair-ud-deen, Isabo nilu Abeokuta ni won
fija tuka leyin ti won kede Ogbeni Olufemi Iyanda Omilani gege bi alaga tuntun.
Idi ni pe opo awon omo egbe to wa dibo
ni won fesun kan awon to seto ibo naa pe won gbabode,ati pe ojooro ni won se
lojo naa, eyi to si mu ki okan ninu won to n je Seun Agbolade Oloburo bo ewu
sile to si bere si ni da ibi ti won ti dibo naa ru.
Ohun taa gbo ni pe ki idibo naa too
bere lawon kan ninu egbe ti loo ledi apo po mo ajo eleto idibo FIBANNEC to
sagbateru idibo naa lati se alupayida fawon to maa dibo. Omo egbe
marunlelaadorin lawon ti won ni won dibo naa, sugbon to je pe awon to ye ko
dibo ju bee lo.
A tun gbo pe won fesun kan awon bii
Wale Dada, Imalian Boi, Abiodun Muibi pe awon ni won wa nibi modaru naa.
Won ni ninu ibo metadinlogoji ti won di
fun Yinka Adegbite to dupo alaga, ibo meta ni won danu, bee ni won so pe ibo
kan soso ni won yo kuro ibo mokanlelogoji ti won di fun Femi Omilani, yato si
eyi, won so pe eru po ninu eto naa.
Eyi lo faa to fi je pe bi won se ka ibo
tan ni won ni Yinka Adegbite to fidi remi ti dide to si dimo Femi Omilani to
jawe olubiri.
Awon nkan idibo to baje |
Ibinu gbogbo ojooro yii lo bi okan lara
awon omo egbe naa, Seun Agbolade ti won tun n pe ni Oloburo ninu to fi yari
kanle pe afi kawon tun ibo naa di nitori awuruju ti won se.
Gbogbo bi won se n di okunrin naa mu lo
n so pe ko si nnkan to jo, ayafi bi won ba tun ibo naa di, eyi lo faa ti won fi
pase pe kawon olopaa FSARS ti won ti pe pe ko waa daabo bo awon oludibo lojo
naa pe ki won maa gbe okunrin naa lo si ago won lati lo sadajo to to fun.
Bawon kan se gbo oro naa, ni awon omo
egbe yooku naa so pe ayafi kawon olopaa maa ko gbogbo won lo si tesan nitori
won ko le mu eni kankan soso lo. Leyin oreyin, won fi okunrin naa sile.
Sugbon eni tawon omo egbe naa da ebi le
lori ju to tun je, akowe eto idibo naa, Dokita Michael Adetunji Prosper topo mo
si Doctor Jega to je okan lara awon agba sorosoro nipinle Oyo so pe ko si
magomago nitori pe bo se ye ko lo naa lawon se.
O so pe ki eto idibo naa too bere lawon
ti ye awon oludibo wo, tawon si yo awon ti ko leto lati dibo kuro, ati pe lati
ose to lo lohun lawon ti n palemo e, tawon si ti le oruko awon to gbapoti
atawon to kun oju osuwon lati dibo.
Adetunji so pe kii se pe wahala kankan
wa bi ko se pe eni to fe da wahala naa sile ti mu nnkan yo nitori pe kaadi
idibo meji-meji lawon fawon oludibo. O ni eni to ba so pe oun ko gba kaadi
meji, ko waa so foun, koun le fi awon kaadi to ku han an.
Lojo naa |
Alaga fidehe egbe naa, Ogbeni Gbenga
Oladunni, Imalian Boy nigba toun naa soro, o f’Olorun seleri pe bo se ye ki eto
idibo lo labe ofin lo se lo nitori ipinle meji otooto ni won ti yan awon to
seto idibo naaa.
O lawon eeyan naa seto naa bo se
ye, sugbon leyin eto idibo naa tawon ti kede eni to jawe olubori, ti eni
to fidi remi si ti dide lati ki eni ti won dibo yanni won ti yan awon, iyalenu
lo je bawon se ri enikan lara awon omo egbe naa to sare wole, to si bere sii da
aga ru, to loun maa da ile egbe ru, ayafi tawon ba tun ibo naa di.
Olumide Awolowo to wa lara awon ti ibo
naa ko te lorun so pe oro atamo lawon eeyan naa n wi, nitori pe oro ara won ti
jo ye ara won.
O loun mo daju pe awon to n korin maa
jo lo, mo n weyin e fun Omilani to wole gege bi alaga naa ni won a tun so pe ki
lo n se e, nitori pe oun ko kere ninu idibo FIBAN to ti n waye lati ojo to ti
pe wa.
Bakan naa ni oludije to fidi remi, Ogbeni
Adeyinka Adegbite, Omo Baba Tisa naa so pe bo tile je awon gbo pe awuruju wa
ninu idibo naa sugbon awon ko le so boya loooto ni nitori pe ibo tawon fee di
lawon koju mo, kii se nnkan min in, ati pe ko si eri tawon le fi ti nidi.
O lawon omo egbe ti yan eni ti won fe
ko je gege bi asaaju won, ati pe nnkan tidibo wa fun ni yen. Bee lo so pe oro
idibo ko ye ko le de bi tawon omo egbe yoo fi koju ija sira won.
Nigba toun naa n soro, Oloye Sunday Ogunsola Tantala so pe lati ojo toun ti n fi awon oyinbo jeun, ko jabo fo moun lowo ri, ati pe eni toun ba tele lakoko idibo maa wole.
Tantala so pe ko si madaru ninu eto idibo naa, eyi to si foju han gbangba pe idibo akoko re e ninu egbe naa to maa lo bo se ye ko lo.
Sugbon nnkan ti a gbo bayii ni pe awon
kan ti so pe awon ko ni wa sipade egbe naa mo, ti won n so pe epe lawon maa se
fawon to ba ranse pe won, sugbon tawon kan so pe ki won je kawon wo nnkan ti
won fee se ninu ipade meji ti won ba se.
Leyin o reyin, ohun taa gbo ni pe ija
lawon olopaa FSARS atawon agbaagba egbe naa to pe won wa nitori ti won so pe
oro owo da ija sile. won ni awon olopaa ko sise tawon ran won pe ki won gbe
Oloburo lo si tesan lati fenu e gbole.
Asiri taa gbo pe o gbe Femi Omilani wole gege bi alaga ni pe, won ni bawon eeyan se ti n sakiyesi pe gbogbo awon to wa leyin e se duro sinu ojo, ti won ko sa kuro ninu ojo to ro lojo naa je aditu nitori ti won so pe o ni nnkan tokunrin naa fi se.
AWIKONKO gbo pe ko si ojo ti Omilani se inawo ti ojo ko nii ro, eyi ti won fi so pe okunrin naa lo ise wa lojo naa ni, ati pe awon kan ti won wa leyin Omo Baba Tisa ko mogba ti won teka fun Omilani nigba ti won n dibo, bee lawon kan so pe oro atamo lasan ti ko lese nile ni.
Awijare lasan ni gbogbo eleyi,ki gbogbo omo egbe OGUN FIBAN se atileyin fun Olufemi Omilani.Ki egbe le ni ilosiwaju.Ire ooo
ReplyDeleteE se pupo
ReplyDelete