Baba Bankole soro buruku ranse sawon agbalagba to n se oselu - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, July 3, 2017

Baba Bankole soro buruku ranse sawon agbalagba to n se oselu

Oloye Saurau Alani Bankole to je baba olori ile igbimo asofin agba ile yi tele, iyen Dimeji Bankole ti so pe ojukokoro lo n yo awon agbalagba tojo ori won ti le ni ogota odun, ti won si tun n se oselu.

Baba Bankole topo eeyan tun n pe ni Katapila soro yi lojo Abameta Satide to koja lo lohun nibi idanilekoo Aawe Ramadan tegbe sorosoro FIBAN eka tipinle Ogun se, to je akoko iru e.

O so pe ko ye ki eni to ba ti le ni ogota odun si tun ni nnkan se pelu oselu bi kii ba se atenuje ati iwa ailemojukuro to ti wo won lewu. O ni odun 2003 loun fi oselu sile to si je koun gbe omo oun Diimeji dide lati ropo oun.

Oloye Suarau ni se lo ye kawon to ti le ni ogota odun kuro nidi oselu nitori pe ko si nkan ti won tun fee se mo, ki won maa fa awon omo won sile ropo won, tori pe awon odo lo ye ki won maa se oselu.

Ninu oro e, o so pe “Kii se pe kii se pe ki won yowo kilanko awon agbaagba kuro patapata, bi ko se pe ki won fi aaye sile fawon tie je won si tutu, iyen awon odo ti a n so pe awon ni ojoola wa.”

Nigba to n sapejuwe, o ni awon oju tawon eeyan ti mo lati ogoji odun seyin naa ni won si tun n ri titi di asiko yi, eyi ti ko si ye ko ri bee. O ni se lo ye kawon naa lo sinmi, ti won ba si lawon omo to nife si oselu, ki won sagbateru won.

“Awolowo di Olori orileede ko too pe ogoji odun; Obasanjo di olori orileede leni odun mokanlelogoji… Asiko ni yi fun eyin odo lati dide loo ledi apo po mo awon to le ran yin lowo.”

O tesiwaju pe kawon odo gan an dide lati ja fun eto won, nitori pe awon ni agbara wa lowo e ati pe bi won ba fe oro tawon eeyan n so pe awon odo ni ojoola orileede yi wa si imuse, won gbodo le awon agbalagba ti won ko fe ire fun won kuro.

Bankole ni bi won ba si lero fee maa da si oro Naijiria, ki won loo je baba isale fegbe oselu won lati maa fun won lamoran nibe, kii se pe ipo to to sawon odo ni won maa maa le kaakiri lati du.


Bee lo so bawon odo ba ko lati loo ja feto won, ki won gbe enu won dake lati maa se maa banuje pe ijoba kan o dara, eni kan ti dagba ju. O ni ki won lo sibe tori pe ko seni to n fun enikan lagbara bi ko se pe se ni won ja feto nibe, iyen niluu Abuja.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI