Ka dupe lowo eni to ri ni to moju, opo
eeyan ni ko wo ibi ti a wa rara, eyi lo ni ibamu pelu bawon to mo riri awon
iroyin lede abinibi to n waye latigbadegba, ti won si n gbosuba kare fun awon
iroyin wa lati osu kinni odun yi ti a ti bere sii gbe orisirisi iroyin jade ni
pereu bo tile je odun 2010 lati wa.
Opo awon eeyan ni won ti bere sii se
sadankata fun IROYIN AWIKONKO to je pe ori ayelujara intaneeti nikan lo si wa
bayii, ti won si n royin bo se n lo lawujo fawon araalu.
Kii se tenu, akoko iru e ni AWIKONKO je
nitori pe ko tii si iroyin lede abinibi to je pe ori ero ayelujara nikan lo wa,
ti won si n mu iroyin wa fawon to ti n wa ona lati maa ka iroyin lede abinibi
won tii se Yoruba.
E ma je ko ya yin lenu pe bi won se n
ka awon iroyin wa lorileede Naijria, bee naa ni won ka a loke okun. Awon
orileede bii Canada, Ukraine, United Kingdom, Brazil, Argentina, United States,
Afghanistan, Manchester United atawon min in ni won ti n kaa IROYIN AWIKONKO,
ti won si n fi ateranse osuba kare fun wa.
Bi won se n kaa lawon orileede ti a
daruko wonyii, bee naa lo je pe won tun n ka a nile lawon orileede ile adulawo
bii Kenya, Malawi, Ghana, South Africa, Togo, Benin Republic, Saudi Arabia
(Dubai) ati bee bee lo.
Bo tile je pe ohun tawon eeyan to n
fiwe ranse si wa n so ni pe ki a tubo je ki aami wa lori awon oro ti a n ko, ko
le rorun fun won lati ka daadaa, ati pe ka gbiyanju lati maa yan omo sidi awon
oro wa, sugbon ti a fi n daa won loju pe igbese ti n lo lori e, laipe igbadun
ara oto n bo lona.
Te siwaju,Omo Yoruba atata.
ReplyDelete