Asiri tu; Asiri nla tawon eeyan ko mo nipa igbeyawo omo Gomina Amosun ati omo Anike Dabiri - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, July 6, 2017

Asiri tu; Asiri nla tawon eeyan ko mo nipa igbeyawo omo Gomina Amosun ati omo Anike Dabiri

Kii se iroyin tuntun mo pe ilu Abeokuta fee gbalejo awon eeyan jankan-jankan lorileede yi ati lawon orileede kaakiri agbaye lojo kejo osu ti a wa yi.

Gomina ipinle Ogun, Ibikunle Amosun ati okan lara awon omo ile igbimo asofin ipinle Ogun tele, Abike Dabiri-Erewa, eni to tun je amugbalegbe aare lori oro ile okeere ni won fee fi omo ta ara won lore lojo Abameta Satide to m bo yi.

Ayomide Amosun toun kekoo gboye gege bi agbejoro nileeko giga kan loke okun lodun 2015 lo fee fowosowopo pelu ololufe e Oladipo Dabiri toun filu Oyinbo sebugbe, sugbo to pada sorileede naijiria laipe yi, nitori ti won so pe won ti jo n fe ara won lati nnkan bi odun merin seyin.

Orisirisi aheso ati awuyewuye lo si ti n lo nipa igbeyawo naa laarin awon omo ipinle Ogun ati agbegbe e, eyi ti AWIKONKO ko se tan lati soo sita faraye.

Sugbon nnkan tawon eeyan ko mo ni pe yato si ilu Abeokuta ti ayeye naa yoo ti koko waye, won tun n lo pari gbogbo eto toku nilu Oyinbo gege bi a ti gbo lati enu awon to sunmo Gomina Amosun, iyen awon ti won ti gba iwe ipe (invitation card).

Inu ogba President Muhammadu Buhari Estate to wa ni opopona Abeokuta si Sagamu, iyen Kobape, Abeokuta ni a gbo pe ipalemo ti pari bayii, ojo naa ni won si n reti pe koo wole de bawon. Bi won ba si se n kuro nibe ni won yoo tun loo kadi e nile ni Mitros House ati Gateway Annex nibi ti won yoo ti se e ni tibile.

Ohun taa gbo ni pe gbogbo eto lo ti to bayii, nitori ti won so pe ayeye awon oloselu ni won fee fi igbeyawo naa se. Lara awon alejo to n si n bo nibi ayeye igbeyawo naa ni Ojogbo Yemi Osinbajo, to je adele aare, Aare orileede yi tele, Oloye Olusegun Obasanjo.

Aare ile igbimo asofin agba nilu Abuja, Senato Bukola Saraki, Onarebu Yakubu Dogara, awon Gomina meedogun atawon agba oloselu lorileede yi to fi mo ile okeere lohun la gbo pe won n bo. Bee la tun gbo pe awon alejo lati orileede China ti de silu Abeokuta bayii.

AWIKONKO gbo pe yato si awon oloselu, awon ojogbon, awon onileese nla-nla atawon min in jake-jado Naijiria lo n bo ni be. Bo tile je pe won so pe kii se gbogbo awon oniroyin won n reti nibe, ati pe won ko fe kiwon fi foto toko-tiyawo naa sita ki ojo naa too de nitori awon idi pataki kan.

King Sunny Ade, K1 De Altimate atawon gbajumo olorin ni yoo forin dawon eeyan laraya lojo naa.

Ayeye yi gan an lo faa ti won ni Gomina Amosun fi tete bere sii se awon ise opopona to ti pati tipetipe ki awon alejo to n bo le mo pe ilu Abeokuta tun ti rewa si, bo tile je pe won so pe Gomina Amosun ti so fawon alase pe oun ti pari awon akanse ise naa, to si je ise tuntun lawon tun sese bere bayii.

Bakan naa la gbo pe Gomina ti kilo fawon amugbalegbe e atawon komisana pe ki won ma se lo anfaani ayeye naa lati ko ja aaye won, ki won duro nibi ti won fi won si.

Sugbon ju gbogbo e lo, aago mewa ni won yoo te pepe eto naa, ti ko si tii seni to so igba ti ayeye naa yoo pari.

AWIKONKO wa n fi asiko yi ki awon ololufe meji naa ku oriire, adura wa si ni pe igbeyawo naa yoo dale, ti adeda yoo si fie bun igbeyawo ta won lore laipe.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI