Bo tile je pe
orisirisi aheso lawon iroyin kaakiri ero ayelujara n gbe kaakiri lori iku to pa
gbajumo agba osere tiata, eni to tun je akoroyin, onkowe, oludari ere, Oloogbe
Adebayo Faleti, sugbon gege bi iwadii ti AWIKONKO se lati fidi oro naa mule,
kii se osibitu UCH ni baba agba eni odun merindinlaadorun naa ku si.
Oloogbe Adebayo Faleti |
Latigba tiroyin iku baba
Faleti ti te AWIKONKO lowo ni nnkan bi aago mewaa aaro oni Aiku Sande nigbese
lati sewadi ijinle ti bere, sugbon bo tile je pe a ko tii pari iwadii wa titi
di asiko ti a sakojopo iroyin yi, ohun to foju han ni pe lakoko ti baba na n we
iwe aaro ni nnkan bi aago mefa la gbo pe o ti eemi ikehin.
Okan lara awon omo e,
Ogbeni Adeniyi Faleti se so, o lowo oun ni baba oun ku si ni baluwe lakoko toun
n we fun un gege boun se maa n se lojoojumo, nitori pe ko le da se nkan mon on
latari ojo ogbo.
Ninu Adeniyi, o so
pe “Baba si sadura pelu gbogbo awa molebi e laaro yi ni, ko too di pe mo mu won
loo we. Emi ni mo maa n we fun baba mi lojoojumo. Baba so fun wa pe awon ti
gbadura s’Olorun pe ko felomin in ropo awon ninu ise tawon yan laayo. Won loo
ti re awon, awon si ti n fee lo sile tipe.
“Leyin taa gbadura
tan, ti baba soro yi, ko seni to fura pe nnkan fee sele, sugbon onikaluku lo n
woo pe kini baba n so yi, ki baba ma sere kere lai mo pe olojo gan an ti wa
nitosi lati mu emi baba lo.
“Mo mu won wo baluwe
gege bi mo se maa se. Nibi ti mo ti n we fun won lowo ni won tun tun oro naa so
pe awon fe ki Olorun ran eeyan kan lati waa pari ise tawon dawo le nitori pe
awon ti se iwon tawon le se.
“Baba lawon fee lo
sile, nitori asiko ti to. Bi won se n soro naa ni mo so fun won pe o ti to, loju
ese ni mo sakiyesi pe won ko min mo. Aya mi ja, mo ni ki lo sele, sugbon won ko
dahun.
“Loju ese ni mo ti
sare pe awon to ku pe ki won waa wo baba o, won ko soro mo o. A pe baba titi,
ko seni to dahun. Kiakia la sare gbe won loo si osibitu University College,
iyen UCH lati loo mo boya atunse si le wa.
“Nigba taa de be
lawon dokita gbe won loo sayewo, ti won so fun wa pe epa ko boro mo. Won ni
elemi ti gba, baba ti dagbere faye. Ko seni to lero pe baba mi le lo lasiko yi,
bo tile je pe orisirisi oro ifura ni baba n so lenu ojo meta yi. A gba pe amuwa
olorun ni, sugbon a o le gbagbe titilai.”
Kii tun se iroyin
tuntun mo pe ojo kejilelogun osu kejila odun yi ni baba Faleti to je omo bibi
Agbooye ipinle Oyo, to gbe ni Obananko, Kuranga nitosi Oyo maa pe odun
metadinlaaodrun, 87years. Opo ise koloonka ni oloogbe naa ti se ko too ku.
Opo awoodu ni baba
ti gba nigba aye e. Lara awon iwe ti Oloogbe Faleti ko ni “Ijamba Odo Oba, Alagbara Ile ati Alagbara Oko, Adebimpe
Ojedokun atawon min in.
No comments:
Post a Comment