Afaimo ki ikunsinu ma bere laarin awon omo egbe osere TAMPAN bayii - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, July 31, 2017

Afaimo ki ikunsinu ma bere laarin awon omo egbe osere TAMPAN bayii

Seyi Crown di igbakeji alaga TAMPAN; asiri to wa nidi e re

Seyi Crown
Won ni tomo eni ba dara o ye ka wi, beeyan eni ba sun won, o ye ka le royin e faraye, eyi gan an lo lo nibamu pelu pelu bawon omo egbe osere TAMPAN nipinle Ogun see fife han si Omoba Patrick Adeleke Adetutu tawon eeyan tun mo si Seyi Crown gege bi igbakeji alaga egbe osere naa.

Gege b’AWIKONKO se gbo, idibo egbe naa waye ni gbongan Yewa Plaza to wa lagbegbe Ibara niluu Abeokuta lo si bere laago mejila ku iseju meedogun geerege bo tile je pe aago mewaa la gbo pe won fi si, sugbon ti won ti koko se ayewo screening fawon oludibo lojo naa.

Ko pe rara ti won fi dibo naa nitori pe oludibo marundinlaadota (45) lawon igbimo elenimeji ti won sakoso eto idibo naa se ayewo won, ti won si rii pe won peregede lati dibo, ko ju iseju mejila lo ti won fi dibo naa.

Nnkan to tun je kidibo naa ya ni pe ninu ipo mejeeji to wa nile ti won gba foomu e, la gbo pe ko salatako pelu won, to si lo bo se ye ko lo, sugbon ti won lo bii iseju marundinlaadota lati sayewo awon iwe idibo naa, ko too di pe won so iye tidibo je.

Leyin ti won ka ibo naa tan ni won so pe ibo mejilelogoji lo gbe Seyi Crown wole gege bi igbakeji gomina, sugbon kii se oun nikan lo gbapoti, omobinrin kan, Saidat Kareem toun wa lati Ijebu North, tibo ogoji gbe oun wole gege bi alukoro egbe naa.

AWIKONKO gbo pe saaju akoko yi ni alaga eto idibo, Omoba Bolaji Amusan, Mista Latin ti so pe ki won too le kede awon eeyan naa gege bii pe won ye fun ipo naa, ibon ti won gbodo ni ko gbodo din ni ogbon. Lesekese naa ni won ti kede won gege lati bere ise gege bi ipo ti won du.

Nigba to n soro, Seyi Crown supe lowo awon omo egbe naa fu akitiyan ati ife ti won ni soun, to si seleri pe oun yoo sise oun gege bo se ye, toun ko si nii soju saaju.

Okan lara awon to gboro naa s’AWIKONKO leti lo so pe afaimo ki ikunsinu ati ijeraeni lese ma bere ninu egbe naa nigba ti won so pe nibi idibo naa ni lawon meji ti won dibo yan lojo naa ti bere sii faini ara won.

Ohun taa gbo ni pe igbakeji alaga eleto idibo, Alaaji Lateef Dehinde nigba to fee kede alukoro naa, iyen Saidat Kareem lo ti fesun kan an pe o pee de ibi idibo naa, o ni ki Seyi Crown gege bi oloye egbe sedajo fun un.

Nigba ti Seyi Crown maa soro, o ni komobinrin naa loo san egberun meji aabo (N2500) naira gege bi owo itanran, nibe ni won so pe inu ti bi Saidat, toun naa n gbadura pe ki olorun je ki Seyi Crown ko soun lowo.

Nibi eto idibo
Se lo dabi eni pe adura Saidat gba nigba ti won ni Alaaji Deinde wa esun si Seyi Crwon lese, to si ni ki Saidat sedajo fun un, iyalenu lo je nigba ti Saidat sare so pe koun naa san egberun marun (N5000) naira, tawon eeyan si pariwo pe ki loo de to fi le to bee.

Awon eeyan to wa nibe la gbo pe won gba Seyi Crown sile, ti won si da owo naa titi to fi pe, lai je pe Seyi funra e yo owo lapo lati fi sile. Eyi lo faa tawon eeyan fi n woo pe afaimo kawon eeyan naa ma bere sii gbogun tira won.

Lara awon to wa nibe lojo naa ni Gomina won, Dajilapa; Alaaji Waheed Ijaduade; Gbenga Oladunni, Imalian Boi, Kayode Akindina; Monsuru Ijayegbemi; Owolabi Ajasa atawon mi in.

Ni bayii ohun taa gbo ni pe Ojoru Wesde ose yi ni igbakeji aare egbe osere naa, Oloye Anther Laniyan maa wa lati bura fawon oloye tuntun naa, kise won le bere ni pereu.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI