Won l’awon oni tirela n binu si Amosun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, June 30, 2017

Won l’awon oni tirela n binu si Amosun

Iroyin to n lo kaakiri igboro bayii ni bawon oni tirela se ti bere ipinu lati fehonu won han si Gomina ipinle Ogun, Ibikunle Amosun latari tikeeti ti won ni won n ja lojoojumo.
 
Gege bi eni to gbe oro naa si AWIKONKO leti se so losan ojo Eti Fraide oni, won ni tikeeti metala lawon eeyan naa n ja lojumo, ti eyo kookan si niye to je. Sugbon ni bayii, won ni Amosun tun ti fee gbe tikeeti min in jade fun won, eyi ti yoo fi je merinla.

Bo tile je pe ise iwadii ti n lo lowo lati bawon toro naa kan soro, ki won si so tenu won bo ya looto ni, sugbon a gbo pe awon eeyan ti fiwe ebe ranse si Gomina Amosun lati ma se je ki ipinu naa wa si imuse.

Bi nnkan ba se n lo ni AWIKONKO yoo mu wa fun un yin. E ku oju lona. E se bi e ti n ka iroyin wa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI