Awon odaran naa |
Gege bi AWIKONKO se
gbo, Lukman Taiwo, eni ogbon odun; Taiwo
Babalola, eni odun mokandinlogbon; David Gbenga, eni odun marundinlogbon; Wasiu
Olaegbe, eni odun merinlelogun; Ojo Aliu, ogbon odun; Taofik Sulaimon, eni odun
merinlologun; Jamiu Taiwo, eni odun mokanlelogbon ati Igwe Ofosile ni won
dena de Sunday ni nnkan bi aago mewa ku iseju meedogun ale ojo naa.
Gbogbo owo owo e,
iyen egberun lona igba (N200,000) naira pelu opolopo kaadi ti won fi n gbowo,
ATM to wa lowo e.
Kii se Sunday lo ni
awon kaadi ATM yi, sugbon ileese banki to n ba sise ni won ko o fun un lati fi
wa awon onibara wa si banki naa, ki oun naa si le gba ipin ti e leyin to ba ti
ri awon eeyan, gege bi adehun to wa laarin oun ati banki naa.
Sugbon bo se n bo
nile ni won lawon eeyan yi loo dena de e, ti won si gba gbogbo eru owo e lale
ojo naa. Ohun ti a gbo ni pe Sunday bawon odaran yi sagidi pupo ki won baa ri
owo owo e gba, sugbon omi po ju oka lo lo je ki won seku pa a.
Kii se pe awon eeyan
yi deede seku pa, sugbon ki asiri won ma baa tu sita nitori ti won so pe Sunday
da gbogbo won mo, ati pe adugbo kan an naa ni won jo n gbe lo je ki won pa a.
Bisele naa se waye
lawon ebi Sunday ti lo o fejo sun awon olopaa Ekun Ajuwon, ti DPO Ogbeni Kazeem
Afolabi si ti foro naa to komisana won, Ahmed Iliyasu leti, latigba naa ni won
ti ran awon otelemuye sita lati mu awon odaran yi.
Gege bi Alukoro
olopaa se foro naa to AWIKONKO leti nirole oni Tusde, o ni aipe yi lowo ba won,
ti gbogbo won si ti jewo pe looto lawon gba owo lowo Sunday, sugbon nnkan to je
kawon pa a ni pe o da awon mo, ki asiri ma baa tu lawon se gbemi e lojo naa.
Ni bayii towo ti te won,
ti won si ti ko won de ogba olopaa to wa ni Eleweran, Abeokuta, Komisana
Olopaa, Iliyasu ti pase pe kawon olopaa esin o koku FSARS ko won lo si ofiisi
won lati lo tesiwaju ninu iwadii.
Iliyasu wa gbawon
araalu lamoran pe ki won tubo maa je kawon olopaa mo nnkan to n lo nipa awon
odaran ladugbo won. o ni ki won ma se bo enu won lati fi odaran han sawon
olopaa nitori pe awon lo n ba ilu je.
No comments:
Post a Comment