Won
ni oogun owo lo fomo naa se
Titi di bi a ti n
koroyin yi ni iya agbebi kan ti won pe oruko e ni Esther Mathew si fi wa tesan
olopaa to wa ni Eleweran nibi ti won ti n sewadi lori esun ti won fi kan an pe
o ji omo oojo gbe pamo titi tomo naa fi ku mo on lowo.
Gege bi AWIKONKO se
gbo, obinrin oloyun kan ni won so pe o lo si osibitu e lati lo bimo lojo
Abameta Satide to koja yi, sugbon nigba to maa di nnkan bi aago marun irole,
alaboyun naa ti bimo, Esther si so fun iya oko obinrin naa pe o ti bimo.
Won ni se lo so fun
iya oko naa pe ko tete lo sile lo o ko awon eru omo wa, ko si pe baba omo
tuntun naa wa. Sugbon nigba ti won maa fi pada de, Esther ti gbe omo naa salo,
ti won ko si rii.
Gbogbo awon noosi to
wa lenu ise lojo naa ni won so pe won ko mo ibi ti Esther to ni Osibitu naa lo
nitori se ni won so pe o gbe omo naa dani nigba to n lo, ti won si wa gbogbo
inu yara to wa ni osibitu naa, ti swon ko ri eni to jo o.
Won pe aago Esther
titi, sugbon ko lo, titi ti ile ojo naa fi su. Okan lara awon molebi oko Abolore
Adeyemi lo soro naa sori ero ayelujara Instagram, to si salaye fawon eeyan bi
oro naa se je.
Lesekese ti won ko
ri Esther ni won ti ranse pe awon olopaa lati gba awon lowo ayederu noosi to ji
omo tuntun gbe salo. Sugbon nigba ti won maa fi ri Esther, oku omo ni won ba
lowo e.
Ohun to so fun won
ni pe oku lomo ti won bi, bo tile je pe o ti so fun won lori aago lojo Aiku
Sande pe omo naa wa lalaafia, ko si nkan to se e, sugbon boro naa se yi pada lo
mu ifura dani pe o ti lo o lo omo naa ni.
Gbogbo awon to gbo
soro naa lo so pe se ni Esther fomo naa se oogun owo ati okiki ni, ati pe oogun
awero lo fomo ikoko naa se, nitori ti won so pe ile akoku kan leyinkule osibitu
e to n ko lowo.
Titi di bi a ti n
koroyin yi lawon ebi ko tii soro lori nkan to sele, sugbon alukoro awon olopaa
nipinle Ogun, Ogbeni Abimbola Oyeyemi ti so pe Esther ti wa ni akolo awon nibi
tawon ti n foro wa lenu wo.
O so pe lesekese ti
won ti gbe Esther de Eleweran ni Komisana, Ahmed Iliyasu ti so pe ki won gbe e
lo si odo awon ajo olopaa to n ri si iwa odaran, iyen SCIID lati se iwadi omo
oku omo naa bo ya loo to lo je omo ti won bi naa lo je ojulowo omo to n so.
No comments:
Post a Comment