Owo ba Habeeb ogbologbo odaran l’Ota - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, June 11, 2017

Owo ba Habeeb ogbologbo odaran l’Ota

Ka ni odomokunrin Habeeb Adekambi ti won so pe ojo ori e ko tii ju odun mokandinlogun lo mo pe awon araadugbo n so oun ni, ti asiri oun yoo si tu sita faraye, boya ki ba ti sun ojo yi siwaju digba miran.

Habeeb Adekambi
Gege bi AWIKONKO se gbo, adugbo kan ti won pe ni Ilupewo, Ositelu nijoba ibile Ota  ni won so pe asiri Habeeb ti tu ni nnkan bi aago meta aabo irole oni tii se Aiku Sande.

Ohun ti a gbo ni pe ile kan ti won n ko lowo ladugbo naa ni won ni Habeeb fo fensi e, to si loo ji awon eru ko nibe laimo pe obinrin kan ti n so oun latigba to ti wole sadugbo naa.

Obinrin ti won foruko bo lasiri yi ni won so pe o tete ke gbajare sawon agbaagba ladugbo naa pe oun ri odomokunrin kan, to fo fensi wonu ile akoku kan, toun si nigbagbo pe ole ni, ati pe o fee ji awon eru ko nibe ni.

Lesekese lawon agbaagba atawon odo ladugbo ti lo o duro de e pe to ba fi maa jade, owo awon lo maa ko si, ti ero won ko si yipada si bi won se ro o nitori pe bi Habeeb se fo jade sita pada lati maa sa lo pelu awon eru to ti ji ko lowo palaba e segi.

Awon eeyan naa si bere sii ko lilu boo bii pe won ti n waa de tele ni, ko too di pe won muu lo sile Baale lati fi too leti pe awon ti mu odaran kan ladugbo, lara awon to maa n ji won leru ko.

Ibinu ni won so pe awon odo adugbo naa fi ju taya sii lorun pelu eru to ji gbe niwaju e pe afi kawon dana sun un titi tie mi yoo fi bo lara e, ko si jona di eeru gudugudu, sugbon Baale naa la gbo pe o so fun won pe ki won ma se idajo lowo ara won, ki won lo fa a le awon olopaa lowo.

Baale naa, Oloye Alaaji Yaya Ajibose nigba to n ba AWIKONKO soro nipa isele naa lori aago, o so pe iyalenu lo je foun bi won se kigbe ole de iwaju ile oun, o ni ibi toun ti n gbategun loun wa. o ni awon nnkan ti won fee fi se ina (electric) loo lo ji.

O so pe ninu oro tawon eeyan so nipa Habeeb ni won ti so pe eni (mat) ni iya e n ta ninu oja Ifo. O ni won so pe oro e kii soju lasan, o lowo aye ninu nitori pe kii se akoko re e towo maa ba.

Habeeb atawon eru to ji
Alaaji Ajibose so pe ori oro e lawon eeyan e wa pe won maa lo se itusile fun un fun ti iwa ole to n ja kaakiri yi. O lawon oro wonyii loun gbo, toun si pase pe ki won lo fa a le awon olopaa lowo, ki won ma se se idajo fun lowo ara won.

O lesekese ni won ti muu lo si ago olopaa ekun Ota ki won tesiwaju ninu ise iwadii won lori oro Habeeb, ki won si fowo ofin muu. O so pe awon n gbiyanju agbara awon ladugbo naa nipa ise aabo ojulalakanfinsori.

O ti e so pe igba kan tawon adigunjale ti waa le leta sadugbo awon, iyen lodun to koja pe awon n bo, sugbon lesekese lawon ti foro naa to gbogbo ileese eto aabo, bii olopaa, fijilante atawon min in leti, ti won si n wa lore-koore lati wa daabo bo emi ati dukia awon eeyan won.

O wa gbawon eeyan lamoran pe ki won ma se pa enu won mo bi won ba kofiri awon odaran ladugbo, ki won tete pariwo won sita ki ise aabo ilu baa tun le kesejare fawon agbofinro.

Fun eri aridaju, AWIKONKO ba Alukoro olopaa ipinle Ogun, Ogbeni Abimbola Oyeyemi soro lori aago lati jeri soro naa, sugbon nnkan to so ni pe oun ko tii gbo nnkan to jo be, sugbon oun yoo se iwadi, toun yoo si jabo fun wa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI