Ose yi ni won yoo sinku Moji Olaiya o - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, June 5, 2017

Ose yi ni won yoo sinku Moji Olaiya o

Gbogbo eto lo ti to bayii lati sinku gbajumo osere tiata Mojisola Christiana Raimat Olaiya to ku silu Canada lojo kejidinlogun osu to koja latari aisa to ba pada lakoko to bimo tuntun eleekeji.

Eto isinku Moji
Gege bi iroyin to te AWIKONKO lowo se so, ola tii se ojo Isegun Tusde ni won yoo gboku ati omo tuntun to sese bi naa de sorileede Naijiria, iyen ni papako ofurufu Muritala Muhammed to wa ni ikeja, ipinle Ekoo.

Nibe lawon ebi, igbimo eto isinku atawon ololufe e miran yoo ti pade awon mejeeji lati tewo gba won bi oko baluu won ba se n sokale laaro. Lesekese ni won yoo si ti gbe e lo sile e lati lo o seto bi won yoo se se isin idagbere fun un.

To ba di aago merin geerege nirole ni won yoo gboku naa lo si gbongan Blueroof ninu ogba LTV 8, Lateef Jakande ni Agidingbi, Ikeja, nibi tawon osere tiata atawon ololufe e kaakiri agbaye yoo ti wo aso dudu lati kedun e nibi eto ayeye ale awon osere ti won fee se fun un.

Nibi eto ayeye ale awon osere naa ni won yoo ti ta aso ti won ti ya foto Moji Olaiya si legberun kan aabo, 1500 naira fawon eeyan.

Lojo keji, iyen Ojoru Wesde ojo keje ti won yoo sinku Moji, AWIKONKO gbo pe ite Ebony Vault to wa ni Ikoyi ni won ti seto lati sin oku naa sii laago mewa aaro.

Kinni kan ti AWIKONKO ko tii ri gbo ni pe boya won ti seto weje-wemu fawon alejo to ba wa paapaa nigba to je pe oku Moji Olaiya kii se oku ofo, o ti bimo meji ko too ku, bo tile je pe iya e si wa laye.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI