Tegbon taburo kan,
Matthew Elegbede ati Sunday Elegbede ni won ti foju bale ejo bayii, lori esun
apaayan ti won fi kan won ni nnkan bi ose meji seyin.
Sunday ati Matthew Elegbede |
Bi e o ba gbagbe,
laipe yi ni AWIKONKO gbe iroyin naa jade pe awon kan sa baba agbalagba eni odun
metalelaadorin, 73years, Oloogbe Adebari Odeyemi lada lori, to si gbabe dero
orun alakeji.
Matthew Elegbede,
eni odun metadinlogbon la gbo pe o fee lo ja okan lara awon ayalegbe baba
Odeyemi lole, to si ti fee yo awon gilaasi oju fere tan, ko si gbabe wole, ko
too di pe asiri e tu sawon araadugbo lowo.
Nibe ni won ti ranse
pe baba onile naa nile e keji to n gbe pe awon ti mu ole, ko waa woo, sugbon
nigba to maa de be, lo rii pe eni toun mo ni Mathew, to si so pe oun yoo lo
foro naa to awon molebi e leti laaro ojo keji.
Nibi ti won ti n
soro naa ni won so pe Matthew ti yo boro mo won lowo, to si loo pe awon egbon e
meji kan, nnkan to so fun won ni pe se ni won paro mo oun, ti won si tun gun
oun lobe.
Nkan ti won lawon
yen gbo niyen, ko too di pe won gbera lati wa koju awon to ni won paro mo oun,
sugbon ni ti won ti n fa oro naa ni won so pe Matthew ti fa ada alaamu yo, to
si fi sa baba naa lori, ko too salo pelu awon egbon.
Lesekese ni AWIKONKO
gbo pe won ti loo foro naa to awon olopaa ekun Agbara leti, ti DPO naa, Ogbeni
Adegbite Omotayo si gbera lati loo ko won, ti owo si ba Matthew ati awon egbon
e meji Funmi ati Sunday Elegbede to je igileyin ogba fun un.
Baba ti won pa |
Ko pe ti won ko won
la gbo pe won fi Funmi sile lago olopaa, sugbon ti a gbo pe baba naa jade laye
leyin ojo meta toro naa sele. Ojoru Wesde to tele ki baba naa too ku la gbo pe
won ti foju awon eeyan naa bale ejo, ti adajo si sun ejo naa siwaju di Monde to
koja lo lohun.
Leyin tawon olopaa
gbo pe baba naa ti ku ni won ti loo so fun adajo naa pe awon fee yi ejo tawon
gbe wa si esun apaayan tori pe baba ti won sa lada lori ti ku.
Okan lara awon omo
baba naa to n je Abiodun, nigba to n bakoroyin wa soro laaro ojo Abameta Satide
to koja lo so pe awon olopaa ko tii gba kawon sin baba awon, nitori ti won so
pe kawon loo mu egberun lona aadota wa lati se ayewo kan ti won pe autopsy foku
baba awon.
Gbogbo igbese lati
ba alukoro olopaa ipinle Ogun soro lori foonu alagbeka e, ti nomba e je 08123822910 lo ja si pabo, nigba ti a pe
e titi di nnkan bi aago meta koja iseju mokan osan oni ti ko lo.
No comments:
Post a Comment