Omo oloye Egba dero kootu l’Abeokuta - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, June 20, 2017

Omo oloye Egba dero kootu l’Abeokuta

Okunrin kan Taiwo Adeboye Sobande to je okan lara awon omo oloye Egba tele, Oloogbe Oloye Surakatu Biobaku Sobande lo foju bale ejo giga kan to wa nilu Abeokuta lori esun pe o yi iwe ogun ebi si odo ara e

Okunrin yii ti Baba e ti figba kan je Osi Egba toun naa tun je oloye lo ti n kawo seyin rojo lori esun naa.

Gege bi AWIKONKO se gbo, won ni latigba ti Baba won, Oloogbe Biobaku Sobande ti ku ni won ti n wa iwe ogun ki won le mo bi won se fee see laarin ara won.

Sugbon leyin o reyin ni won rii pe Baba naa ko se iwe ogun kankan sile ko too dagbere faye, lai mo pe okunrin ti won pe ni Taiwo Sobande ti loo se ayederu iwe ogun, eyi ti won loo se fun ara e nikan.

Won ni gbogbo ile ebi, eyi to je to Baba won ati tawon min in lokunrin naa ti fee ta tan, to si n leri pe ko seni to le ye oun lowo wo.

Awon ile ti won ni Oloogbe naa ko si agbegbe Arepo nitosi Ibafo, ni won lokunrin naa ti so loruko ara e, "Chief Taiwo Sobande Estate."

Awon molebi naa wa ro ile ejo pe ki o pase pe ki Taiwo Sobande jowo gbogbo ogun to wa lowo, eyi to ti n sakoso e lati ojo ketalelogun osu keji odun 2001.

AWIKONKO tun gbo or Oloye Taiwo Sobande naa tun ti n ran awon alagbapa lati pa agbejoro ebi won, iyen Ogbeni George Oyeniyi.

Oyeniyi nigba to soro naa niwaju adajo, Majekodunmi, lojobo Tosde ose to koja, o so pe "Yato si pe oro naa wa nile ejo, okunrin naa ko dekun lati maa ta ile molebi won, bakanna lawon kan tun n dunkoko mo mi lati pami ti mi o ba jawo lori ejo yi."

Adajo Majekodunmi wa so fun agbejoro naa pe ki won foro naa to awon olopaa leti nitori pe, ise won ni lati gbogun ti awon ajagungbale.

Atipe ofin to de awon ajagungbale nipinle Ogun ko faaye sile fun enikeni lati gba ile lona aito to lodi sofin to de iwa ajagungbale.

Gbogbo igbese lati ba Oloye Taiwo Sobande soro lati le gbo oro lenu e lo jasi pabo, lori bo se so pe oun ko setan lati ba oniroyin soro.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI