Titi di bi a ti n
koroyin yi lawon to mo iyi gbajumo onisowo nni, Alaaji Adelusi Balogun Shittu,
eni topo mo si Balocool si n fi ateranse ranse sii lati kii ku ayeye ojo ibi
odun marunlelaadota, 55years to se logunjo osu yi, iyen June.
Balocool |
Gege bi iroyin to te
AWIKONKO lowo se so, won ni ojo malegbagbe lojo naa je fokunrin naa nitori
tawon ojogbon ateeyan pataki laarin awujo ni won wa a ba okunrin topo mo si
Balocool yi sayeye naa nile e to wa ni Osogbo, ipinle Osun.
Omo bibi ipinle Ekiti
nigba to n soro lojo naa dupe lowo Olorun Allah fun ti aanu to ri gba nitori pe
opo ni won pe odun naa to je pe won ko tii ni nkan toun ti ni, tawon min in si
ti ku, sugbon o ni kii se tigberaga bi ko se oore ofe Allah.
Okunrin oniwa irele
Balocool so pe opo ojo lo ri ro, ti ile si ti fimu nitori pe awon ipenija ati
adojuko toun ba pade nigbesi aye oun, paapaa nigba toun wa ni kekere ko see
fenuso, sugbon ola Olorun lo gbe oun duro di asiko yi.
Alaaji Shittu tun so
pe lara oore ofe toun ri gba loun naa ti n saanu awon eeyan pelu nnkan ti Adeda
foun. O so pe bo tile je pe isoro ti orileede yi koju laarin odun to koja si
asiko yi, fee mi oun naa, sugbon sibe, Allah si gba akoso, tenu oun si gba ope.
Bakan naa lo wa
gbawon eeyan lamoran pe ki won maa lo anfaani ojo ibi won lati fi dupe lowo
Olorun Oba nitori pe Oun nikan lo le fun eeyan ni anfaani lati ni emi gigun
pelu alaafia.
Bee lo so pe ki won
maa gbiyanju lati maa saanu awon to ba ye, nitori pe bi eni to n ba Olorun
dokoowo ni aanu ri, ko si seni to ba Olorun dokoowo to padanu ri.
Lojo naa la gbo pe awon
agba nidi esin Islam tokunrin naa n se gbe akanse adura kale fun un nitori ipa
to n ko lawujo paapaa lati gbe esin Islam laruge.
No comments:
Post a Comment