Titi di bi a ti n
koroyin yi lawon ti soobu won jona ni oja Osiele nijoba ibile Odeda ipinle Ogun
ko tii fi tara-tara gbadun nitori ti won so pe oja to le ni milionu mewaa lo
jona di eeru ninu awon soobu to jona lojo Aiku Sande ijeta to koja yi.
Gege bi AWIKONKO se
gbo, ni nnkan bi aago mejila aabo oru ni won so pe ina deede la ninu soobu kan,
eyi to sakoba fun soobu meje ti won so pe oja to wa ninu won le ni milionu
mewaa naira.
Bawon ti soobu won
jona se n gbera sanle sunkun bee ni won n pariwo gbese nitori ti won ni awon ko
le so pato nnkan to fa ki ina seyo to yoo si jo awon oja di eeru.
AWIKONKO gbo pe ko si ina ijoba lasiko tisele naa bere, eyi ti won le fi
ri dimu pe boya ina ijoba lo faa.
Bo tile je pe awon
toro naa kan so pe awon ko mo nnkan tawon fee so latari ibanuje ati ironu to
gba okan won, sugbon omo okan lara awon eeyan naa to bakoroyin wa soro so
pe iyalenu lo si n je fawon.
Arabinrin Funmilola
so pe oun ko le so pato nnkan to le sokunfa ijamba ina naa tori pe awon kii
dana ninu soobu, bee si lawon kii tan ina atupa.
Ibi isele naa |
O ni lesekese tariwo
ina yi gba Osiele kan lawon eeyan ti bere sii jade lati dawo e duro sugbon to
je pe pabo loro naa ja si. O ni yato si oja iya oun, soobu awon aburo oun meji
to je pe awon nkan jije lo n ta ba isele naa lolawon oja to ba ijamba naa, bee
lo so pe awon oja to wa ninu awon soobu yi le ni milionu mewaa tori pe iso awon
elewe omo atawon oloja purofison ni.
Bakanna lo rawo ebe
sijoba lati boju aanu iranlowo wo awon tori pe awon ko ni agbojule miran, ibi
tawon ti n jeun niyen tawon si n san owo ori won deede.
Nigba to n
b’AWIKONKO soro, Jagunmolu ilu Osiele, Oloye John Adio Oyeleye ni nnkan bi aago
meje aabo aaro ojo naa, o so pe iru nnkan bee ko tii sele ri ninu oja naa, ati
pe ko seni to le so pato nnkan to fa ijamba ina yii.
O loju oorun loun wa
ti won fi wa ji oun, lesekese lawon kan ti so pe kawon loo pe awon panapana
sugbon oju ona loun ti ni ki won pada tori pe o seese ki won ma tete dawon
loun, ko too di pe awon gbe igbese lati pana naa.
O loo seni laanu pe
aso ko bomoye awon soobu mejo to je pe opo milionu leru to jona ninu ijamba
buruku naa.
Jagunna Osiele |
Oloye Oyeleye ni bo
tile je pe Kabiyesi ko si nile, sugbon oun atawon Oloye ilu yoo foro naa to
leti lati gbe igbese to ba ye.
Asiwaju Aje Osiele,
Oloye Osoko Kolawole nigba toun naa bawon eeyan naa kedun pelu ibanuje okan so
pe ogbe okan nijamba ina naa je foun, tori pe ilosiwaju oja naa loun wa.
O loun si koja ni
nnkan bi aago mejo ale ojo Abameta Satide lati sabojuto awon soobu, toun ko si
ri apeere pe iru nnkan ajalu bayii le sele.
Oloye Osoko niyalenu
lo je foun nigba ti won foro naa toun leti pe oja jona, toun ko fo enu toun fi
gbera lati wa wo o.
Oun naa lo asiko naa
lati rawo ebe sijoba ipinle Ogun pe ki won bawon da si oro naa, o loun
nigbagbo pe ti Gomina Amosun ba gbo gege bo se je eleyinju aanu, yoo ran awon
lowo.
No comments:
Post a Comment