Looto lopo awon araalu gba pe ofe ko ni beeli beeyan ba de ago olopaa, bo tile je pe ojoojumo lawon oga olopaa kaakiri orileede yi si n so pe ofe ni beeli. Agbenuso fawon olopaa nipinle Ogun, Ogbeni Abimbola Oyeyemi nigba to n ba AWIKONKO soro nibi iforowero laipe yi ni ofiisi e to wa ni Eleweran Abeokuta, o tenumo on pe looto ni beeli je ofe. O ti e so pe odaran leni to ba sanwo beeli lago olopaa. Yato si eyi, Oyeyemi soro nipa bo se bere ise olopaa atawon nkan min in to sokunkun nipa eto aabo. E ka bi iforowero naa se lo.
Abimbola Oyeyemi |
AWIKONKO:
A mu ikinni wa fun un yin lati IROYIN AWIKONKO, nje a le mo yin lekunrere?
OYEYEMI:
AbdulMojid Abimbola Oyeyemi loruko mi ti iya ati baba mi so mi lojo ti won bi mi.
AWIKONKO:
Bawo le se bere igbesi aye yin ko too di pe e di alukoro fun ileese olopaa?
OYEYEMI:
Omo bibi Iragbiji Olokemeji nipinle Osun ni mi. Mo lo si ileeko alakobere
Methodist to wa ni Iragbiji, ki n to o tesiwaju ni ileewe girama Baptist to wa
ni Iragbiji naa. Mo gbe ile daadaa ki n too kuro, mi o si le so ile nu. Leyin
yen, mo lo si Yunifasiti Ilorin ti mo si pari ni odun 1995. Odun 1999 ni mo
darapo mo ise olopaa. Ko pe ti mo darapo mo ileese olopaa ni mo lo si ileewe
olopaa, Police College, leyin ti mo pari ni mo lo si ipinle Eko. Ipinle Eko yi
ni mo wa titi di odun 20011. Odun yen ni oga olopaa lorileede yi nigba yen,
Afiz Ringin lo ran gbogbo awa ti a niwe eri nla, iyen Degree pe ki won ran wa
lo kekoo sii. Idi ni yi ti won fi fun wa ni igbega, ti won fun wa ni okun ASP
(Assitant Suprintended of Police). Igba ti a pari leyin odun kan, won gbe mi wa
sipinle Ogun, ti won si fi mi se igbakeji alukoro olopaa nigba yen, Omoba
Muyiwa Adejobi. Nigba to di odun 2016 ti igbega de fun alukoro olopaa yi, iyen
Adejobi ti won gbe e lo si eka keji ileese olopaa ti a mo si Zone 2 nipinle Eko,
igba yen ni Komisana wa, Ahmed Iliyasu so mi di alukoro olopaa nipinle Ogun.
Latigba naa la si ti n sise alukoro titi di asiko yii.
AWIKONKO:
Lopolopo igba lawon maa n so pe awon ko le gba ki omo awon sise olopaa latari
awon idi kan, ki lo faa to fi je pe ise olopaa yi gan an le yan laayo?
OYEYEMI:
Beeni, paapaa julo nile Yoruba wa nibi, a kii fe nkan to ba le ju ogede lo. Ko
po ninu awon omo Yoruba to je pe ojuboro, kii se agidi lo fi darapo mo ise
olopaa. Emi naa nig ba ti mo darapo, mo mo nkan toju mi ri, ariwo ki lo n wa lo
lo kun eti mi nigba naa lohun, sugbon nkan to ba wu ni lokan leeyan maa se. kii
se pe airi ise lo mu mi wo ise olopaa, mo kuro nibi ise kan lati darapo mo ise
olopaa ni. Opo awon eeyan lo si ya lenu pe ki lo de ti mo fi iru ise gidi bayii
sile, to je pe ise olopaa ni mo wa a lo darapo mo. Mo nife si ise yi lo je ki n
darapo mon on. Latigba ti mo ti wa nileewe alakobere ni mo ti feran awon ise to
je pe ki a wo aso egbejoda, iyen Uniform. Mo n se Boyscout, Man-O-War pelu awon
ise kan to nii se pelu eto aabo. Kekere nise olopaa ti wa lokan mi.
AWIKONKO:
Oju wo lawon obi yin fi wo nigba naa, ati pe iha wo ni won ko sii?
OYEYEMI:
Eeeh, se e mo pe ti won ba pariwo titi, sugbon ti won ri pe eniyen ko woo do
won, nkan to ku ni pe kin bere sii gbadura pe ki Olorun se e ni ona e, tipatipa
ni (Esu) fi n feran (Sango).
AWIKONKO:
Bawo wa ni irn ajo yin gege bi ise olopaa?
OYEYEMI:
Ko si ise ti ko si oke isoro kan tabi ikeji nibe, sugbon ti eeyan ba ti le
duro, to si ni afojusun, eeyan a kesejare nibe. Lakoko naa, opolopo lo n so pe
iwo ti o keko gboye, to n sise gidi, ki lo wa de to je pe ise olopaa ni mo tun
un lo darapo mo gege bi contable, ki ni mo ro debe, sugbon Yoruba ni ti a o ba
ku, a maa je eran to to erin. Ara ise to daa pupo nise olopaa, iyen bi awon
eeyan wa ba se n se gege bo se ye ki won se e. irin ajo mi gege bi ise olopaa,
igba lo le die wa nibe, awon asiko to si tun derun naa wa nibe, ni ile aye se
wa niyen.
AWIKONKO:
E o menuba boya e ko e ko eko nipa ede Yoruba, gege bi awon oro to n jade lenu
yin?
OYEYEMI:
Bi e ba woo, gege bi mo se so fun un, mo pe nile daadaa, mo si sunmo awon agba
tori pe awon agbalagba lo to mi dagba. Awon ti ma sa baa maa n ba sore, awon to
to mii bi lomo ni. Odo won ni mo ti n gbo orisirisi oro kanka ko too ba mi lara
mu. Nkan ti a n gbo lenu awon agbalagba lawa naa fi n soro.
AWIKONKO:
Nje e nigbagbo gege bi eto aabo pe e n daabobo ara yin, bii pe e n di ara yin
lamure tabi nnkan min in?
OYEYEMI:
Olorun nikan ni olori alaabo. Bi eeyan soogun titi, ewe a sunko lojo kan,
sugbon ise Olorun nikan ni kii sunko. Adura nikan ni ko ni ojo taa fun pe ko
sise da ti oloyinbo n pe ni Expiry Date.
Ko da oogun oyinbo gan an ni ojo to maa fi sise da, sugbon titi lai ni adura.
Ati pe se e mo pe awon to n sise buruku, emi to wa pelu ise ti won n se yen, ni
yoo maa fi won le awa olopaa lowo, nitori pe okunkun ko le bori imole mole, eni
to wa ninu imole gbodo bori eni to wa ninu okunkun. Ko digba teeyan ba n so
onde mora, tabi to n gbe ijapa korun, Olorun nikan lo le daabo bo eeyan tori pe
Oun nikan ni olori alaabo.
Oyeyemi |
AWIKONKO:
Ki ni awon adojuko yin ki e too depo tee wa yi?
OYEYEMI:
Adojuko ko pe meji, bi ko se adojuko to wa fun gbogbo olopaa kaakiri. E mo pe
ko si bi elede yoo se maa jejo ti esun oorun ko nii si nibe. Bi olopaa ba se n
kan to da fenikan, eni yen yoo maa yin olopaa yen, sugbon enikeji to lo fi ejo
sun, ti olopaa rii pe ko sejo nibe, ko ni fojuure wo olopaa yen, nitori pe
igbagbo e ni pe olopaa yen ti gbowo. Bo se ri gan an niyen. Eni ti ko fun
olopaa ni sile marun un ri lati ojo to ti dele aye, bi nkan ba sele sii, ti
olopaa sise won gege bi ise, yoo so pe olopaa ti gbowo ni. Iru awon adojuko bee
wa nile, to si po repete. Opolopo ejo ti won n mu wa ba olopaa lo pe ko soju
olopaa. Sugbon ejo ti enikinni ro, ti enikeji naa so tie, ni olopaa maa sise le
lori, to si gbe igbese, sugbon eni ti igbese yen ko ba ba laramu, oto ni nkan
ti yoo maa so kaakiri.
AWIKONKO:
Nje e ti e le so pato ise kan ti e se, to fee mi yin, tabi ti e le so fun wa pe
e o le gbagbe?
OYEYEMI:
Ise po ti a ti se seyin sugbon eyokan ti mi o le gbagbe, ti mo si maa n ranti
daadaa, kii se pe bo ya inira kan wa lori ise yen, sugbon bi ise yen se gba lo
je ki n maa ranti nigbagbogbo. Arakunrin kan lo fee soda titi lagbegbe Alapa ni
Suurulere, nipinle Ekoo, bi moto kan se gba niyen. Eni to fi moto gba a yi lo
wa gbe sinu moto bii pe o fee lo toju e, lo ba lo ju sibi kan, ibe ni eni yi ku
si. Ko si seni to mo nomba moto yi nitori pe idaji ni, aaro kutu ni. Sugbon
nigba ti mo maa debi ise lojo keji, won ti ko leta sile pe emi ni ki n lo se
iwadi lori e. Mi o mo moto, mi o mo igba ti nnkan sele, mo waa bere sii ronu pe
bawo ni mo se fee sise yi, ko si yori si rere, sugbon pelu ogo Olorun, Olorun
fun mi se. mo se iwadi yen, mo pada ri eniyen mu, mo ri moto yen mu, ti mo si
gbe eniyen lo si kootu. O je ise kan ti mo maa n ranti lore-koore.
AWIKONKO:
Gege bi olopaa, nje ise kan wa ti e maa n fi ranti bi abamo pe ki lo mu mi se
e?
OYEYEMI:
Mi o figba kankan kabamo pe ki lo de ti mo fi sise yi ri, ise to wu mi lokan
lati se nise olopaa. Mi o tii ba pade, mi o si ni ba a pade. Bi eeyan ba n sise
kan, ti nkan to se die ba wa sele, to wa bere sii kabamo pe ki lo de toun fi se
e, to ba je idi ise min in, nnkan to ju iyen lo le sele sii nibe. Ife okan se
koko nidi ise teeyan ba yan laayo.
AWIKONKO:
Opolopo igba ni won maa n so pe ofe ni beeli sugbon, sugbon nigba ti eeyan ba
dele ejo, won maa n so pe ki won san owo beeli gege bi owo itanran. Ki le le ri
so sii?
OYEYEMI:
Beeli ile ejo yato si beeli ago olopaa, ko si nkan to kan olopaa ninu beeli ile
ejo. Sugbon nkan ti a n pe ni beeli ago olopaa ni pe, ki eni ti won ba mu pe o
se ese kan, ko wa eni to le duro fun un lai san owo kankan, nitori ti nkan ba
tun sele lojo iwaju, eni yen ni won a lo o mu. Eni to ba lo san owo beeli,
odaran loun gan an funra e, tori pe o fun olopaa lowo riba niyen. Eni to fun
enikan lowo eyin ati eni to gba, odaran lawon mejeeji. Sugbon opolopo igba
lawon eeyan wa kii farabale, awon gan an ni won a maa beere lowo awon olopaa pe
ki lawon fee se, ti won a si maa fi owo lo awon olopaa pe kini kawon mu wa.
Nigba ti olopaa naa ko go, oun naa a ni ki won lo mu egberun lona ogun naira wa.
Mo n tenumo fawon eeyan wa pe ibikibi ti won ba lo, ti won ba n beere owo beeli
lowo won, ki won pe ofiisi oluuleese olopaa lati fi ejo sun.
AWIKONKO:
se ka so pe awon araalu lo n ti owo sawon olopaa?
OYEYEMI:
Opolopo igba awon araalu lo n ti owo sawon olopaa lenu, nigba ti won ba n beere
pe eelo ni kawon loo mu wa. Kini yi ti wa lokan awon eeyan wa ti won ba pe won
pe ki won wa beeli eeyan won kan lago olopaa, igbagbo won ni pe owo ni won n
beere, ti ko si ri bee. Awon ni won a maa beere pe eelo ni kawon mu dani tawon
ba n bo. Ti awon gan an ko mo pe oran lawon n da, tori pe eni to fun un yan ni
owo riba, ati eni to gba owo riba, odaran lawon mejeeji.
AWIKONKO:
Ki wa ni ajosepo to wa laarin awon araalu ateyin olopaa?
OYEYEMI:
Eto aabo kii se nkan ti olopaa nikan le da se, bi araalu ko ba fowosowopo pelu
olopaa, olopaa ko le se nkankan. Tori e gan an la se ni igbimo kan ti a n pe ni
Police Community Relations Committee, PCRC, awon ni won je gege bi ategun
laarin araalu atawa olopaa, nitori pe ajosepo to manyan lori gbodo wa laarin wa
pelu araalu. Bi araalu ba n fee to aabo to pe ye, won gbodo je ki ajosepo gidi
wa laarin wa. Olopaa ko le wa nibi gbogbo nigba gbogbo lai kii se Olorun. Ise
araalu ni lati pe olopaa, ki won si so pe awon ri oju kan to sajoji, tabi apejo
kan to sajeji si won ladugbo won, sugbon ti ko ba si ajosepo kankan laarin won,
bawo ni won se fee pe olopaa, tani won fe e pe. Ti won ba si pe wa, awa ko le
mo nkan to n sele ni adugbo won. sugbon ti a ba tete gbo, a maa sare lo sibe
lati lo wo nkan to n sele, ti a ba si rii pe apejo won lodi sofin, dandan ni ki
a fi ofin gbe won, ki a si pe won lejo, ki o too di pe won lo huwa odaran to
maa ta ba araale ati ara-oko.
AWIKONKO:
Opo awon kan wa to je pe won o mo owo mo ese ninu esun ti won ba fi kan won,
gege bi won se maa n so pe oriyeye niimogun?
OYEYEMI:
Ko si eni ti olopaa le mu pe o daran, to maa so pe beeni. Gbogbo eni ti e ba
mu, dandan ni ki won so pe awon ko mowo, awon ko mo nkankan nipa e, sugbon pelu
iwadii to muna doko, opolopo ninu awon ti won so awon ko mo nkankan yi lo je pe
leyin iwadi, la maa too sese mo pe awon gana an ni igileyin ogba, awon ni olori
ninu iwa ibaje. Laipe yi la safihan awon odaran kan lojo die seyin to je pe
okan ninu awon odaran yi, ibon ti won lo taa gba lowo, lo so pe ohun ko mo nkan
ti a so, ohun ko ri ibon ri lati ojo ti won ti bi oun, sugbon leyin ose meji,
awon akegbe e ti won jo huwa buruku yi, awon ni won loo ja moto gba lowo oga
agba ileeko fasiti Crawford. Igba taa ri awon yooku mu, a tun pe awon oniroyin
pe ki won wa a wo won, funra awon oniroyin gan an ni won ri ti won si daamo pe
won ti muu ri, to si so pe oun ko mo nkankan, lo sese wa so pe igba ti won ko
tii ri awon toku mu lo je koun so bee. Igba yen la sese mo pe oun lo wa moto ti
won lo fi dena de okunrin yen, ti won si ja moto owo e gba. Oun ni olori won to
n pese ibon fun won. eyi lo fa to fi je pe ko seni ti won le mu, to le so pe
looto loun se e. Eni ti a ba si mu, leyin iwadii ti a rii pe ko ni nkankan an
se pelu iwa odaran, dandan ni ka fi sile ko maa lo.
AWIKONKO:
Bawo le maa n se awon iwadii yin?
OYEYEMI:
Ise iwadii pin si orisirisi ona, o po repete. Bi iwa odaran ba se waye, bee na
ni olopaa yoo se sewadi e. awon ise iwadi kan wa to je pe ero igbalode, iyen
tekinologi (technology) la maa n fi
se e. awon kan wa to je pe o gba ka gbera lati ilu kan lo sibo min in. awon kan
wa to je pe o gba ki a lo foro wanilewo lenu awon to wa ni agbegbe yen.
Orisirisi iwadii lo wa. Awon idawii kan wa to je ileewosan la maa ti lo se e,
ki a too le mo okodoro oro. Fun apeere, eni ti won pa, bo ya won fun loogun je
ni, lara awon iwadii bee ni ki won gbe iru eni bee lo sile iwosan, ki won yee
wo, iyen toloyinbo n pe ni autopsy ti
won si le fidi okodoro mule pe oogun lo gbe je to fi ku. To ba ri bee, a tun sese
wa bere iwadii pe odo talo ti jeun gbeyin, iru ounje wo lo je, to ba seese ti a
ri ajeku iru ounje bee, a maa le gbe ajeku ounje naa lo fun ayewo boya ounje
naa ni.
AWIKONKO:
Nibo ni ise eto aabo de duro
OYEYEMI:
Ti e ba wo ipinle Ogun ni nnkan bi odun meji si meta seyin, e o rii pe adinku
wa lori iwa odaran repete, a ni nnkan taa fi n ye e wo, ti a n pe ni crime
statistics ti ma fi n se akosile bi iwa odaran se n lo. Eyi lo maa n je ka mo
bi iwa odaran se po to laarin ilu lodun kan.
AWIKONKO: Nje e ti e le fi ise
le omo bibi inu yin lowo?
OYEYEMI:
Ko si nkan to buru nibe, to ba ti wuu lokan lati se. a le fi tipa mu esin de
odo, sugbon a o le tipa fun un lomi mu. Ko si nkan to di mi lowo lati da omo to
ba wu lati sise olopaa duro. Ise yi naa ni mo n se, oun naa si ni mo fi n toju
e.
AWIKONKO:
Nje o dara ki olopaa se oselu?
OYEYEMI: Ko si nkan to buru lati se oselu, sugbon olopaa
to ba fe se oselu gbodo bo aso olopaa sile, ko si loo se e. ijoba to ba ti wa
lori aleefa ni ti wa. Agbofinro la wa, a kii se oloselu.
No comments:
Post a Comment