Nurudeen fipa ja ibale odi l’Ajura - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, June 11, 2017

Nurudeen fipa ja ibale odi l’Ajura

Bi kii ba se opelope awon eni-bi-eni, eeyan-bi-eeyan to tete ranse sawon olopaa pe ki won tete wa gba Nurudeen Akintoye sile lowo awon to n luu ni, iroyin ti a n ko yi ko ni a o ba maa ko, nitori ti won so pe die lo ku ki won pa a.

Nurudeen Akintoye
Gege bi AWIKONKO se gbo, Ni nnkan bi aago mesan kuseju meedogun ale Ojoru Wesde to koja yi ni won so pe Nurudeen to sese pe ogun odun tan omodebinrin eni odun mejidinlogun kan ti won foruko bo lasiri, sugbon ti won so pe odi ni, ko le soro, bee ko gboro wonu igbo, to si fipa ba a lo po titi to fi jai bale e lagbegbe Ajura nijoba ibile Obafemi Owode, ipinle Ogun.

Gbogbo ariwo ti won lomo naa n pa sita lakoko naa, ko seni to gbo, nitori wi pe ko le soro sita, sugbon leyin ti won ni Nurudeen te ara e lorun tan, lo ba bere sii be e pe ko ma binu, ko ma so sita fenikankan, ati pe to ba so sita, oun yoo pa ni.

Bomo naa se sunkun dele, niya e beere lowo e pe ki lo se e, talo naa, to si fowo si abe e fun iya e lati wo o, nibe ni won so pe iya e ti ri eje to n jade lati abe e.

AWIKONKO gbo pe biya e se ri eje labe e, lo pariwo sita pe kawon araadugbo gba oun, ti won si beere lowo e pe talo se kinni fun un, ile Nurudeen lo mu won lo, to si toka sii pe oun lo fipa ba oun sun ninu igbo.

Igbaju-igbamu ni won koko fun Nurudeen bo se fe e soro, to si bere sii bebe pe ki won pa oun sile, ki won daso asiri boun, nitori pe ise esu ni, oun ko mo emi buruku to gbe oun wo lati se kinni naa fun un.

AWIKONKO gbo pe se lawon eeyan bere sii lu Nurudeen bi eni lu adigunjale towo palaba e segi, afi bi eni pe won ti n wa a de tele ni pelu iya ti won ko fun un lale ojo naa.

Awon kan ti aanu se nigba ti won lu Nurudeen lo sare pe awon olopaa lati waa gba a sile ki won ma baa pa.

Alukoro olopaa ipinle Ogun, Ogbeni Abimbola Oyeyemi nigba to n soro naa fun AWIKONKO ni nnkan bii aago merin ku iseju meedogun osan oni Sande, o so pe DPO ekun Owode Egba, Sheu Alao lo o lewaju awon olopaa lati lo o mu Nurudeen lesekese tiroyin ti te lowo.

O lopelope wi pe Sheu Alao ko foro naa fale rara, ko too gbera, oro naa ko ba ti yiwo nitori ipo to bawon nibi ti won ti n lu Nurudeen, to si tete gba a lowo won, ko too mu lo si tesan lati lo o foro wa a lenu wo.

Tesan ni Abimbola ti so pe Nurudeen ti so boro naa se je, ti won si gbe omo naa lo si osibitu jenera ti Owode Egba fun itoju to peye, ti won si tun se awon ayewo kan fun un.

Gbara tiroyin naa ti kan si Komisana, Ogbeni Ahmed Iliyasu lo ti ranse pe ki won maa gbe bo ni Eleweran fun itesiwaju ninu iwadi, to si pade pe ki won tare e lo si eka olopaa to n ri si lilo awon omo nilokulo, iyen anti human trafficking and child labour unit lati sise naa.

Iliyasu wa gbawon araalu lamoran pe ki won dekun lati maa se idajo lowo ara won bi won ba mu enikeni nitori nnkan to lodi sofin orileede yi ni, paapaa ofin to de iwa odaran.

O ni kii se gbogbo awon ti won ba fura si naa lawon le so pe odaran ni won, bi ko se pe ile ejo nikan lo le so leyin ti won ba ri eri aridaju.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI