Gbajumo osere tiata
nni, Alaaji Taiwo Hassan topo mo si Ogogo Kulodo ti bu enu ate lu Gomina ipinle
Ogun, Ibikunle Amosun lori oro to so pe awon Yewa n sagbateru adije Tekobo lati
dije dupo gomina nipinle naa.
Ogogo soro yi nibi
eti idanileko ti Aawe Ramadan to waye ni gbagede Asade Agunloye to wa nilu
Ilaro lakoko to n bawon akoroyin soro, o so pe bo ba je looto ni Amosun fee
gbaruku ti Yewa lati depo gomina, ko ye ko maa so awon oro abuku naa jade lenu.
O lawon mo nkan
tawon n se nitori pe awon da ara won mo, atipe Senato Solomon Adeola, iyen YAYI
je eni tawon bu ola fun gidigidi nitori pe omo bibi Yewa ni, kii se Tekobo
rara, ojulowo omo Yewa si ni.
Ogogo ni omo awon
lati Ishaga Orile ni agboole Pahayi ni Yayi je, kii se Tekobo ti Gomina Amosun
pe nita gbangba. O ni bo ba je looto ni Amosun fe ki Yewa gba Gomina lodun
2019, ko ye ko fi oju saaju soro naa.
Bi e o ba gbagbe,
lojo Isegun Tusde to koja ni Gomina Amosun so pe boun ba ti e fee tele ipinu to
wa nile pe Yewa lo kan ti won n pariwo, kii se Tekobo ti won lo o gbe wa loun
maa bawon fowo si.
O ni bi adije kan ba
jade lati Ogun Central, oun ko nii fowo si, oun yoo tako lakoko ipolongo. Bi
enikeni ba jade l’Ogun East, o seese koun ma tako lakoko ipolongo idibo, sugbon
oun ko nii fowo si. O ni adije to ba jade l’Ogun West iyen ni Yewa loun yoo
tele, sugbon kii se adije Tekobo ti won n pariwo e.
No comments:
Post a Comment