Nitori egberun meji Adeoye ja omo e sihoho ni Sagamu - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, June 20, 2017

Nitori egberun meji Adeoye ja omo e sihoho ni Sagamu

Owo olopaa ipinle Ogun ti te baba alailojuuti kan ti won poruko e ni Adeoye Oreyemi, eni odun mokanlelogoji ti won ni se lo so omo e bi eran, to si tun ja sihoho omoluabi nita gbangba.

Adeoye
Gege bi AWIKONKO se gbo, ojule kesan, adugbo Dokun ni Ewuga nijoba ibile Sagamu ni won ni esun ti Adeoye fi kan omo e, omodun metala yi ni pe o ji oun ni egberun meji naira, eyi to so pe omo naa ti fee maa jale lati kekere, toun ko si nii gba.

Eyi ni won loo bi Adeoye ninu, to si woo mo taa foruko bo lasiri yi sita gbangba, to si ja sihoho, ko too di pe o so sekeseke mo lowo ati ese pelu kokoro to fi tii pa, to si bere sii wo kaakiri igboro adugbo naa.

Ko too di pe Adeoye ja omo e sihoho yi, la gbo pe o ti koko lu ebi eran ewure, to je pe gbogbo bi won se so pe awon araadugbo naa n ba omo yi bebe ni won ni Adeoye so fun won pe ko seni to le so boun se maa to omo bibi inu oun foun.

Jija ti won ni Adeoye ja omo yi sihoho ni won loo bi awon toro naa soju e ninu e, ti won si loo foro naa to awon olopaa ekun Sagamu leti, ti DPO Aduroja Moses, si sare loo lati loo gba omo naa sile.

Lesekese ti won lawon olopaa de be ni aanu won ti se omo yi nitori ti won so pe inu agbara eje ni won ti ba omo yi, ti won si sare gbe e lo si osibitu kan ti won pe ni Owokoniran to wa nilu Sagamu fun itoju to peye, nibi ti won ni omo naa wa titi di bi a ti n koroyin yi lowo.

Foto Omo naa
Agbenuso funleese olopaa ipinle Ogun, Abimbola Oyeyemi nigba to n soro naa fun AWIKONKO nirole oni, o ni iyalenu loro Adeoye si n je foun nitori pe oun ko tii ri iru baba to daju to bayii, tori pe se loo fe pa omo naa nitori owo ti ko to n kan.

O ni Komisana awon, Ahmed Iliyasu lesekese to ti gbo soro naa, lo so pe ki won je ki iwadii naa je ni kiakia, ki won le tete gbe Adeoye lo sile ejo pelu esun eni to fee paayan, iyen Attempted to Murder.

Bee lo tenumo on pe oun ko nii kawo bonu, koun maa wo awon to fe maa tapa sofin orileede yi nipa iwa odaran. Bee lo ro awon araalu pe ki won ma se bo enu won lati maa je kawon olopaa mo bo se n lo ladugbo won.


2 comments:

  1. Aye ma le o
    O ye ki won pa okunrin yi danu ni

    ReplyDelete
  2. Hmmmm! Aimoye iru won.
    Se e ti gbagbe eyi to lu omo e pa ni Port Harcourt losu to koja ni
    Ewon gbere lo to siru won

    ReplyDelete

PÍN-IN KÁÀKIRI