Beeyan ba wa ni kootu
Majisireeti kan to fikale si Isabo nilu Abeokuta ipinle Ogun l’Ojobo Tosde to
koja yi, yoo mo pe ko si ese ti ko ni ijiya labe ofin nigba ti won bere sii ka
esun si odomokunrin Mojeed Sanusi lese pe o fee sekupa ore e nibi ti won ti n
ja.
Mojeed omodun
mokandinlogun ni won so pe oun ati okunrin kan ti won pe oruko e ni Mufutau
Sikiru jo n fa wahala, sugbon ti won so pe se ni Mojeed loo yo ada to si fi sa
Mufutau lori.
Gege bi AWIKONKO se
gbo, ojo ketala osu yi ni won so pe oro ti ko to nkan sele laarin Mojeed ati
Mufutau ni nnkan bi aago mesan aabo ale ladugbo kan ti won pe ni Isale Jagun,
Iberekodo nilu Abeokuta tawon eeyan si n la won.
Gbogbo bi won se ni
won n la won lawon mejeeji ko gbo, ko pe e ni won ni Mojeed sare wole, ti won
si ro pe oro naa ti pari sibe, sugbon iyalenu lo je nigba ti won ri ada lowo
Mojeed, to si so pe afi koun gbemi Mufutau.
Awon agbaagba to wa
nibe ni won sare di Mojeed mu pe ko ma daran, sugbon esu to gbee wo lale ojo
naa, ko je ko ronu pe oro naa le gbe oun dogba dele ejo, lo ba sa Mufutau lada
lori.
AWIKONKO gbo pe bi
ada naa se ba Mufutau lori, se loo subu lule, to daku, ni wonba sare gbee lo si
osibitu to wa nitosi fun itoju, nibi ti won so pe okunrin naa si wa titi di bi
a ti n koroyin yi.
Lesekese ni won ti
loo foro naa to awon olopaa leti, ti won si loo mu Mojeed, ko too di pe won gbe
was ile ejo. Agbejoro awon olopaa, Ogbeji Sunday Egbejiale so fun adajo ileejo
pe ese ti Mojeed se tako iwe ofin odaran ipinle Ogun todun 2006, ati pe Mufutau
si wa losibitu nibi to ti n gba itoju.
Onidajo naa,
Arabinrin Oriyomi Sofowora nigba to n se idajo naa so pe oun ko tii le ejo naa,
sugbon ki Mojeed sa egberun lona igba ati aadota (N250,000) pelu oniduro meji.
No comments:
Post a Comment