Ilumooka osere tiata to maa n lo gbogbo ara e sinu fiimu bi eni pe ko
sona atije miran fun un mo, Toyin Aimakhu ti so pe oun ti di atunbi kuro ninu
iwa buruku to fee gbemi oun tele.
Toyin Aimakhu |
Toyin soro yi lakoko to n dahun ibeere nileese telifisan kan laipe yi fun
ti fiimu Alakada Reloaded to sese gbe jade latari awon ipenija to ti ba pade
nigbesi aye e, ti ko le e gbagbe titi lai.
O so pe die lo ku koun gbemi ara oun nigba toro aye oun dojuru
patapata, ti ko si salabaro foun toun le foro lo. O ni ironu wahala to ba oun
yi lo so oun di amugbo, toun ko le se koun ma mu oogun oloro kokeeni lojumo.
Toyin so pe boun se n fa taba, bee loun n mu kokeeni bi eni mu omi,
nitori iku loun n wa kiri nigba naa tori pe oun ko nironu meji ju boun yoo se
gbemi ara oun latari oro aye oun to dojuru.
O lojoojumo loun sun ekun adasun bo tile je pe opo awon to n ri oun
nigba naa lo n beere pe ki lo se oun, bo tile je pe ko seni to duro lati ran
oun lowo, tori pe tonikaluku lo wa lara e.
O ni isoro yi lo gbe oun pade Seun Egbegbe to si je pe se lo n doju ti
oun kaakiri. O ni kani oun fara bale pelu oko oun tele nigba naa ni, ati pe bi
ironu oun se ri nigba naa ko faaye sile foun lati ronu daadaa rara.
Sugbon ni bayii, obinrin naa dupe gidi lowo Olorun to ra emi oun pada
nitori pe igbe aye toun n gbe niisinyi ti yato si ti tele, oun ko si le mu awon
nnkan buruku toun n mu tele mo.
No comments:
Post a Comment