Oloogbe losibitu |
Adugbo kan ti won n
pe ni Abatabutu, Odugbe nijoba ibile Ado-Odo Otan nipinle Ogun ni won so pe
Odomokunrin tojo ori e ko tii ju ogun odun lo, Matthew Elegbede fe loo jale
lojo Aiku Sande to lo lohun ni nnkan bi aago mewa ku iseju mewa, ti asiri e si
tu sawon araale to fee ja lole naa lowo.
Gege bi AWIKONKO se
gbo, won ni nibi ti Matthew ti n yo gilaasi ojo findo, iyen louvers ni won so
pe o ti jabo lu obinrin to ni yara to fee gba wole lori beedi, tiyen si taji,
to fi pariwo ole.
Won ni se ni Matthew
duro gbogbo bi won se n pariwo ole, ko salo tawon araale naa fi jade sita, ti
won si muu mole. Asiko naa ni won ranse pe baba to nile naa, iyen Oloogbe
Ogbeni Albert Adebari Odeyemi, eni ti won so pe oju oorun lo wa ti won fi loo
pe.
Nigba to n ba
AWIKONKO soro lojo abameta Satide to koja yi, obinrin to ni yara naa, Arabinrin
Victoria Omiata so pe oju oorun loun wa ti gilaasi fi jabo lu oun lori beedi
toun sun si, o laya oun ja loun fi sare dide bo sita toun si bere sii pariwo
ole.
Lesekese lo so pe
awon araale ti jade lati loo wo eni naa, sugbon iyalenu lo je pe omo naa ko
salo, ti won si mu sita, o ni ariwo tawon n pa lo je kawon araadugbo waa wo
nkan to n sele, ti won si so pe omo adugbo ni.
Victoria |
O so siwaju pe ko ju
iseju marun to kuro laarin awon lawon gbo ariwo moto tirela nla, to n sare wa
bo, to si waa di oju titi niwaju ita pe ko si moto to maa koja, bo se sare bo
sile niyen to si n fi ada le awon kaakiri.
Obinrin naa so pe
Oloogbe Odeyemi nikan lo duro pe kawon gba ada naa lowo nitori pe se loo tun
loo pe awon egbon e meta kan wa lati wa fa wahala naa, ti won si bere sii lu
awon eeyan nilukulu.
O loun ni Matthew
koko fi ada naa le wonu igbo to je pe Olorun lo yo oun, leyin to pe die loun
gbo pe o fi fada naa sa Baba Odeyemi lori, ti won si ti gbee lo si osibitu kan
to wa ladugbo fun itoju.
Alaroye gbo pe, se
ni Matthew loo pe awon egbon e, Funmi ati Sunday to n gbe lodo won pe awon kan
fi gilaasi sa oun lowo, won si tun lu oun, lo je kawon yen naa dide lati waa
gbesan, lai beere boro naa se je ko too di pe won bere sii fada le awon eeyan
kaakiri.
Akanji Fatolu |
Okan lara awon to
sunmo oloogbe naa, eni to tun je alaga egbe awon ajorin (welder) ti egbon
Matthew, Sunday je igbakeji e, Ogbeni Akanji Fatolu nigba toun naa n soro lori
isele naa, so pe ibi toun fegbe lele si ni oloogbe Odeyemi ti waa pe oun pe won
mu ole nile keji e, kawon jo lo.
O so pe bi omo ni
baba naa se mu oun, to si je pe ko si ojumo kan ki baba naa ma de soobu oun,
nitori oun nikan ni oludamoran toun le so pe oun ni. O ni odo oun ni baba naa
wa di nnkan bii aago meje aabo ale ojo naa, sadede loun tun ri won ni nnkan bii
aago mokanla n loolu.
Akanji so pe idi ti
won fi waa ba oun ni pe, won ni won ti wa awon ebi Matthew lo sile, sugbon won
ko ba won, won lawon n wa nomba ti won le pe egbon Matthew, iyen Sunday si tori
awon jo n se egbe kan naa ni lo je ki won wa boya oun le fun won.
O lawon tun pada wa
won lo sile tawon ko si ba won, kawon too tun pada, o loju titi niwaju ita
tawon wa lawon ti ri tirela to n sare bo, o so pe kani awon ko tete sa segbe
ni, ko ba fi tirela naa kolu awon, ati pe se loo fi tirela naa di oju titi pe
moto kankan ko nii koja.
O ni kani oun mo pe
oro naa maa le to yen ni, oun ki ba ti duro, sugbon se loun kuro nibe, o ni ko
tii ju ogun iseju toun pada dele ni won tun wa pe oun pe won ti sa baba lada
lori, toun si pe Sunday lati beere nkan to sele lowo, sugbon nkan to so ni pe
won ti sa aburo oun naa lowo.
Oloogbe nigba aye e |
O ni leyin tawon
kuro nibe lawon eeyan baba loo foro naa to awon olopaa leti, ti won si so pe
won bo tile ba ti mo. O so pe nigba tile mo toun so fun Sunday pe won sa baba
gan an lo n beere lowo oun pe talo sa.
O laaro kutu lawon
olopaa Atan ti wa ko won, sugbon nigba ti won ri pe oro naa koja agbara won lo
je ki won ko won lo si tesan Ilaro nibi ti won ti fesun kan won.
Ohun taa gbo ni pe
Sunday, Funmi ati Matthew lawon olopaa ko, ti won si foju won bale ejo lojoru
wesde to koja, sugbon se ni adajo naa sun igbejo miran si ojo Aje Monde ana,
lai mo pe baba naa maa ku.
Abiodun |
Nigba toun n soro,
okan lara awon baba, Abiodun Odeyemi to so pe Ore nilu Ondo loun wa nigba ti
won pe oun ni nnkan bii aago mejila pe won ti sa baba oun lada lori, ti won si
tun salaye oro naa foun, toun si seleri pe oun yoo yoju.
Abiodun so pe nigba
toun maa de lojoru Wesde to koja, osibu jenera to wa ni Victoria Island nilu
Ekoo ti won gbe baba oun lo loun ti loo pade won, o nibe ni won ti so pe kawon
loo ya sikani ori baba oun.
O ni se lawon sare
loo wa owo, iyen egberun lona ogbon naira tawon fi ya kinni naa, nibe ni won ti
je kawon mo pe eje tit a si baba lopolo, to si nilo ki won sise abe fun won.
O loro bawon se maa
sare wa owo lati sise abe naa lawon so lojobo Tosde mojumo Fraide, ko too di pe
baba gbemi mi, o loju ese loun tun ti so fawon aburo oun pe ki won loo so fawon
olopaa pe baba ti ku, ki won le mo bi won tun se maa gbe oro naa.
Abiodun so pe awon
ti seto lati sin baba sugbon awon olopaa so pe awon ko tii gbodo sin in nitori
awon gbodo sayewo kan ti won pe ni autopsy lati mo boya ada ti won fi baba lo
seku pa won looto.
Kehinde, Iyawo oloogbe |
Okunrin yi ti e je
ka mo pe ipalemo ayeye ojo ibi ni baba n se lowo, to ri o ni baba pe oun losu
to koja pe ojo kokandinlogbon osu gan an ni baba naa maa pe odun
metalelaadorin, 73years.
Iyawo baba naa,
Arabinrin Kehinde Odeyemi nigba toun naa n fomije b’Alaroye soro so pe baba
sese jeun tan, o si ti sun ko too di pe won ranse wa pe awon pe won mu ole nile
keji, tawon si gbera lati lo.
O ni aso inura,
toweeli lo wa nidi baba to fi loo bawon. O so pe igba ti won bere sii fi ada le
won loun sa wa sile, sugbon iyalenu lo je nigba ti won so foun pe won ti sa
baba lada lori.
No comments:
Post a Comment