Enikuomehin |
Gbogbo eto lo si ti to tan bayii, ti redio
naa yoo bere ise ni pereu nitori pe opolopo milionu ni won fi ko ileese redio
naa to wa ninu ogba ileeko FUNAAB, ti awon igbimo atawon osise ileese redio naa
se jo sowo po lati gbe redio naa kale.
Gege bi AWIKONKO se gbo, awon irinse
kan ti won pe ni “Complete Digital Studio” ni won ko wa sibe lati ileese Clyde
Broadcast Products Limited to wa nilu Glasgow, United Kingdom. Eyi lo si fee je
ki ileese redio naa yato gedengbe laarin awon fasiti metadinlogun to nileese
redio ti won.
Bo tile je pe ori ayelujara ni redio
naa wa tele, tawon eeyan ti n je igbadun e lagbaye, sugbon ni bayii, eto ti
pari lati bere ise lori afefe.
Nigba to n soro lori awon ohun elo ti
won fe maa fi sise, ti won ti ko wole, alabojuto ileese redio naa, Ogbeni Ayo
Arowojolu so pe inu osu karun odun to koja ni redio naa bere lori ero ayelujara
to je pe kaakiri agbaye ni won ti n gbo.
O so pe laarin igba naa si asiko yi,
awon to n teti si redio naa lojoojumo le ni egberun kan, ti won si n das awon eto
ti won n gbe jade sita. O ni akosile tawon se nipa awon to n gbo redio naa je
ko di mimo pe yato si orileede Naijiria, awon orileede bii United Kingdom,
United States, Canada, Qatar ati Belgium ni won ti n gbo.
Arowojolu so pe ipa tawon akekoo n ko
nileese redio naa ko se e ko kere nitori pe awon ko je ki awon naa owo to po
fun ise ojoojumo ti won n se, o ni anfaani lo tun je fawon akekoo to ba wu lati
maa soro lori afefe.
Bee lo so pe ipa ti redio naa yoo ko
laye awon akekoo atawon eeyan nilu Abeokuta ati agbegbe e kii se kekere tori pe
ise iwadii lawon yoo maa tun fi redio naa se, tawon eeyan yoo si ma kekoo nibe.
Ayo Arowojolu |
Nigba to n so pe ise ko nii duro lati
je ki redio naa figagbaga laarin awon ileese redio to wa nilu Abeokuta. Owa lo
akoko naa lati dupe lowo Adele Giwa ileeko naa, Ojogbon Ololade Enikuomehin fun
ti ipa ribiribi to n ko lati je ki ala awon wa si imuse.
Bee lo so pe opo aaye ni won ti ya soto
ninu gbogan ile igbimo fasiti naa fun redio naa, ki ise won le tubo rorun, ti
won si tun ti fi iwe ranse sawon igbimo lati tubo fowosowopo pelu won.
AWIKONKO gbo pe ki won too ko awon irinse ileese
redio de lati oke okun ni won ti yan awon igbimo ti yoo maa sakoso ileese redio
naa, lara won si ni, Ojogbon Victor Olowe AMREC gege bi alaga; Ojogbon Kolawole
Adebayo; Ojogbon Helen Bodunde; Ojogbon Eniola Fabusoro.
Awon min in tun ni Ojogbon Biodun Badmus; Arabinrin
Emi’ Alawode; Arabinrin Atinuke Adiyeloja; Ogbeni Ayo Arowojolu ati Arabinrin Adeola
Oke.
No comments:
Post a Comment