Ko sigba ta o ni ku - Itu Baroka - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, June 10, 2017

Ko sigba ta o ni ku - Itu Baroka

Eni ti mo mo daadaa ni, to si mu ise tiata lokunkundun. Ko feran ki a maa dogbon si nkan ti ko ye ka dogbon si. O feran otito pupo, to si maa n duro de nkan to nigbagbo ninu e. Pasito Ajidara je eni kan ti gbogbo osere nipinle Ogun paapaa nilu Abeokuta ko nii gbagbe titilai.
 
Ko si nkan to n sele ninu egbe osere tiata bi ko se pe asiko ti to lati pada sodo eni to da won. Gbogbo eda ti Olorun da lo maa ku lojo kan. Ko si iberu kankan lokan awa osere bi ko se pe a je eni ti awon araalu mo daadaa.

Won si n feran wa loorekoore, o je ki ife wa wa lokan won pupo tori e lo fi je pe ti won ba ri nkan to sele ti ko da, o maa n ko ipaya ba won pupo. Gege bi eeyan, eni ti asiko e ba to lo maa ku, lo maa lo.

A o yato si kapenta, a o yato si mekaniiki, a o yato si birikila, sugbon ariwo kii po ti won ba bi osere tiata nitori ise won ko gbe won si oju aye pupo, ohun lo maa je ki won maa beere pe ki lo n sele.

Sugbon ohungbogbo to ba n sele naa, o n fe adura ni. O wu wa ki Ajidara dagba ju bayii lo, sugbon kii se omode mo, ko kii se pe o sanku, nitori pe eni ti ko to pasito Ajidara lojo ori ti lo, ti aaye ope si yo sile fun wa.

Abe aburada kan soso naa la jo wa, iyen TAMPAN, atipe a ti jo wa legbe ANTP ri to si je igbakeji alaga nigba yen. Ajosepo to dan monran lo wa laarin wa.

Pasito Ajidara ti se ere labe egbe osere mi ti a pe ni Itu Baba Ita Productions, o je ki n mo pe bi ise ba dele, eni to maa n fi gbogbo ara sise ni. Ebun ise yen wa lara gidi gan an to si n je kawon eeyan mo.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI