Kii se iroyin tuntun mo pe ayeye itunnu aawe ti waye, o si ti koja lo,
sugbon iyalenu kan sele ni Yidi ti Gomina ipinle Ogun, Ibikunle Amosun ti loo
kirun lojo naa lati fi pari aawe olojo mokandinlogbon ti won bere lojo
ketadinlogun osu to koja.
Amosun pelu okan lara awon omo naa |
Yidi kan to wa ni ladugbo Lantoro niluu Abeokuta ni Gomina ti loo kirun
lojo kirun lojo naa, iyen lojo Aiku Sannde to koja yi, pelu awon agbaagba leka
oselu, to fi mo oga olopaa ipinle Ogun, Ahmed Iliyasu, ati pe odoodun lo maa n
lo sibe lati loo kirun, paapaa lasiko odun Ileya.
Bo tile je pe opo awon eeyan ni ko foju si ohun to sele yi, sugbon
iyalenu lo si n je fawon kan toro naa soju e nitori ti won so pe Gomina funra e
lo ri awon omokunrin kekere mejeeji yi he.
Lakoko ti Alaaji Liadi Orunsolu to je Imaamu ipinle Ogun n kadi oro e
nile, ni won sadede mu awon omo kekere meji tojo ori won ko tii ju odun marun
un lo siwaju, ti won si so pe awon omo naa ko mo ibi tawon obi won wa mo.
Lesekese ti Gomina ti ri awon omo naa lo ti so pe ki won dawon omo naa
jokoo, funra oun loun yoo fi iroyin naa sita lakoko toun ba n soro, ti Alaaji
Orunsolu si kadi oro pe kawon omo Naijiria maa fi ife ba ara won lo, ki won yo
oro eleyameya kuro.
Awon omo naa |
Bi Gomina Amosun se dide, lo sare loo gbe eyi to kere ju ninu awon omo
mejeeji yi, omo naa tojo ori e ko tii ju odun merin lo, to si gbe e soke pe oun
ri awon omo meji kan he o, won ko si mo ibi tawon obi won wa.
Bi Gomina se n soro yi lawon to wa ni Yidi lojo naa pariwo “haaaaaa”
leekan naa, a fi bi eni pe won ti se riasa tele lori, tawon eeyan si bere sii
foju wo awon omo won nibi ti won wa.
Ohun to je kawon obi awon omo yi tete mo pe awon omo awon ni, ni bi
Gomina se daruko won, sugbon taa foruko bo won lasiri. Lesekese ni egbon okan
lara awon omo yi ti dide lati loo mu aburo e, sugbon tawon olopaa Amosun daa
duro pe ko le koja, ayafi ti Gomina ba setan.
Ko pe e ni egbon omo keji naa tun de, ti won si so foun naa pe ko lee
koja lo sibi ti Gomina wa, ko lo ni suuru titi wi won yoo fi setan.
No comments:
Post a Comment