Ife ni Olorun fi da egbe TAMPAN sile - Olori Adeola - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, June 3, 2017

Ife ni Olorun fi da egbe TAMPAN sile - Olori Adeola

Gbajumo oserebinrin nni, Alaaja Mujidat Adeyemi tawon eeyan mo si Olori Adeola ti so pe ko si wahala ninu egbe osere TAMPAN lorileede Naijiria, paapaa nipinle Ogun.
Olori Adeola
Olori Adeola soro naa laipe yi nilu Abeokuta nigba to n bakoroyin wa soro, o so pe ko si nnkan to n je ede aiyede tabi gbonmisi-omioto laarin awon osere egbe naa nitori pe ife ni Olorun fi da egbe naa sile nigba ti won daa sile.

O so pe ife ti won fi da egbe naa sile lawon fi n ba ara won se po laarin awa won ti ko si je ki ikunsinu wa laarin won.

Nigba to n soro lori iku awon osere meta to tele ara won laipe yii, Olori Adeola so pe “ti a ba wo ojumo to mo loni, a maa gbo ibi tawon eeyan ti n bimo repete, bee la a maa gbo ibi tawon eeyan tun ti n ku naa repete, ibi to kan gun si gege bi won se je olokiki, lo faa tawon eeyan fi mo wi pe irawo kan ja ninu egbe osere.

“Aimoye iru e bee kaakiri, sugbon tori pe won o mo won ni ko je ki won mo nkan to n sele. Telo n ku, alaso n ku, babalawo n ku. Orisirisi eeyan lo n ku lojumo”

Bee lo so ninu oro e pe “Ko si ede aiyede kankan laarin wa ko too ku, ko si si konunkoho laarin awa omo egbe osere TAMPAN rara titi di asiko yi. Ife ni Olorun fi da egbe TAMPAN sile.”

Bakan naa lo soro lori iku Pasito Ajidara pe “Se e ri Pasito Ajidara, iku e se gbogbo wa ni kayeefi, sugbon a wa nigbagbo wipe, Paisto Ajidara ti de ibudoko ti e, o lo sinmi ni. A o le so pe bai lo se ri lokan wa, nitori pe gbogbo igba ti e ba pade e, oro iyanju bi igbesi aye eeyan yoo se da lo maa maa so. Ko huwa pe ka padanu e rara. O dunmi gan an.

“Ki la fee so nipa Pasito Ajidara ti a o ni ri. Mo ko itan kan, ti mo si ti pinu lasiko ti mo n ko itan yi lowo pe Pasito Ajidara ni mo fee lo, sugbon nigba ti ise na ba wa fee bere, ti mi o ri eni tokan mi fe, se mi o wa ni ranti won ni? Titi aye ni mi o le gbagbe pasito Ajidara nitori awon iwa won si mi.”

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI