Idi ise tiata ni won ti la mi lohun – Olori - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, June 5, 2017

Idi ise tiata ni won ti la mi lohun – Olori

Gbajumo osere tiata, to tun je okan lara awon omo egbe sorosoro nipinle Ogun, Queen Toyin Adetola Adeniji tawon eeyan mo si Olori ti so pe idi ise tiata lawon eeyan toun ba pade ti la oun lohun, koun naa too bere sii soro, toro si da saka lenu oun.

Olori
Queen Toyin to ti kopa ninu orisirisi fiimu agbelewo bii; Eru, Sisi Onigarawa, Oku Ijoba, Ija Yemoja, Oba Elesan, Pemisire to je akoja fiimu tie gan-gan to se lodun 2012 atawon mi in soro yi lose to koja.

O so pe nigba toun koko bere, bo tile je pe ile iwe Federal College of Education, Abeokuta loun wa nigba naa, sugbon oun kii soro, jeje loun maa n lo atipe oun maa n sere, toun si mo iwon ara oun.

O loro yipada nigba toun darapo mo ise tiata lodo oga oun Aare Yemi Adegunju, eni to ko oun bi won se n sara loge, bi won se n korin, bi won se n jo ati bi won se n duro niwaju ayaworan, kamera, nitori pe eru maa n koko ba oun ni.

Queen Toyin so pe nigba ti won bere sii fi iwosi lo oun, tawon ti ko to oun maa maa soro soun bi eni pe awon ju oun, bo tile je pe oun ba won lenu ise, ti won si n se bi oga, sugbon nigba ti ara oun ko gba a mo, lo je koun naa lahun, to naa si bere sii soro.

O ni ojoojumo loun maa sunkun nigba naa, ti won a si maa beere pe ki lo n pa oun lekun, ko seni to too pase ninu awon to n kose lowo, nitori pe se ni won a maa da won kaakiri bi eran tabi omoodo atipe oun ti bawon ru eru ni lokesan ri daadaa, toun ko si le ko o.

Obinrin naa so pe oun ko nii lokan nigba toun wa ni kekere pe ise tiata loun maa se toun ba dagba, o ni ise noosi tori pe dokita ni baba oun, bee lo so pe ise awon to n karoyin lo tun wu oun lokan lati se.

Lojo kan lo so pe Aare egbe TAMPAN, Omoba Dele Odule pe oun nigba to ri oun boun se n soro, lo so pe won ti la emi naa loun, iyen nigba ti a wa ni lokesan. O lawon nkan to jo oun loju lo n deru ba oun nigba naa loun.

Bakan naa lo so pe awon adojuko toun n ba pade nidi ise tiata ti agbara oun ko fe e gbe mo lo mu oun sun seyin die, to si mu oun lo o darapo mo egbe sorosoro nitori pe ise agbo awon amuludun wu oun pupo, oun ko si fee fi sile. O nidi ise orin loun fee koko ya si, sugbon ko le si ere nibe foun lo je koun ya sidi ise sorosoro.

O lawon eeyan ti kenu ife soun ri ni lokesan, sugbon Olorun fun oun ni ogbon agba lati fi yo ara oun lowo awon okunrin to fee fe oun nigba naa nitori ki won le foun nise, bo tile je pe o so pe ko sibi ti ise o si, kii se nidi ise tiata nikan niru e wa.

Nigba to n soro lori inagije Olori tawon eeyan n pe, o ni bo tile je pe inu fiinu kan toun ti se Olori fun Baba Ogunmajek ni won ti n pe oun ni Olori, sugbon idile oba loun ti jade, akobi obinrin loun tun je, to si je ki oruko naa ro oun pupo denu ise tiata.

O lawon fiimu kan wa nile toun n sise lori e lowolowo bayii, bi eto oro aje orileede yi se ri ni ko je ko tii jade sita, sugbon laipe, ise naa maa jade.

O wa gbawon eeyan lamoran paapaa awon obinrin nidi ise naa pe ki won ni afojusun, ko digba ti won ba feyin lele fokunrin kan ki ona won too la.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI