Iroyin to n lo
kaakiri igboro paapaa nile Yoruba bayii ni ti ayeye olodoodun kan to maa n waye
ni ileewe giga Federal College of Education, FCE Osiele to wa nilu Abeokuta,
ipinle Ogun lojo keje osu keje to n bo yii.
Iwe ipe |
Ayeye naa ko pe
meji, ohun ni Ogo Oodu ti Egbe Osere Ogo Oduduwa, eka eko ede Yoruba maa n sagbateru
e lodoodun lati fi gbe ogo Yoruba laruge, ti won si maa n fi anfaani e fawon
eeyan jankan-jankan lawoodu.
Gege bi AWIKONKO se
gbo, ona ara-oto layeye todun yi fee gba waye nitori pe gbogbo eto lo ti to ni
ti imurasile won.
Opo awon oba alaye
nile Yoruba bii Olu-Itori, Oba Abdulfatai Akorede Akamo; Oba Oluwasesan
Ogunmuyiwa, Elejio tilu Ejio; Oba AbdulRasak Adewusi, Oni Ijowun tilu Ijowun;
Oba Ezekiel Alani, Olososun tilu Ososun atawon min in ni yoo wa nibe.
Nigba to n for naa
to AWIKONKO leti, Aare egbe osere ogo Oduduwa, Ogbeni Sanni Arewa so pe awon
osere bii Odunlade Adekola, Toyin Adegbola, Asewo to re Meka ati Sahee Osupa,
Afeez Eniola, Kunle Afod yoo wa nikale lojo naa.
O si awon yoo fi
aami eye awoodu dawon eeyan lola lojo naa, bee ni ere ori itage, ijo bata, ijo eyo
ati ere sango lawon yoo safihan e fawon eeyan to ba wa lojo naa, gege bi eto
tawon ti la kale.
No comments:
Post a Comment