Ero ayelujara ti da opolopo idile ru – Aye-Nkanju - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, June 3, 2017

Ero ayelujara ti da opolopo idile ru – Aye-Nkanju

Aderin posonu osere tiata nni, Ogbeni Moses Olanrewaju tawon eeyan mo si Aye-Nkanju ti so pe ero ayelujara (social media) ti da ko lonka idile ru latari awon ayederu iroyin ti n ko sori e.
 
Ayenkanju
Aye-Nkanju soro yi nilu Abeokuta laipe yi lakoko to n b’AWIKONKO soro lori isoro to n koju awon osere latari ero ayelujara, o so pe ero ayelujara ti ba opo nkan je to je pe Olorun nikan lo le tun un se.

O ni boya awon eeyan to n lo anfaani ero ayelujara ko ni imo ati eko to ye kooro to lari bi won se n lo, lo fa to fi je pe won kii bere ki won too gbe awon nkan ti won bag bo sori e.

O ni kii se pe o le ba ise to n lo geere je, bi ko se pe o ti dori ise awon eeyan kodo, o si ti da aimoye idile ati ebi ru.

O tesiwaju pe bawon eeyan to n lo bag bo oro kan, kaka ki won jokoo lati ronu, ki si beere ibeere ki won too gbe kiri, o ni won ko nii se be, ni se ni won maa fi ti won kun un, ti won a si maa tan kaakiri. 

O so pe kii se osere tiata nikan ni won n fi ero ayelujara tabuku e, bi ko se awon to ba ti loruko lawujo, iyen gbajumo, ilumooka ni won ti fib a won loruko je lopo igba to je pe Olorun nikan lo le ko won yo.

O sapejuwe ti ayederu iroyin ti iku Moji Olaiya tawon kan so pe won ti gbe de lati Canada, Aye-Nkanju so pe won ko tii gbe oku naa de nitori awon idiwo kan, sugbon iyalenu lo je nigba ti won n gbe ayederu iroyin naa kaakiri pe won ti gbe e de.

Nigba to n gbawon eeyan lamoran lori awon ayederu iroyin ti won n gbo, okunrin naa so pe kawon eeyan yara lati gboro, sugbon ki won lora lati gba a gbo. “Won ni yara lati gboro, lora lati fesi, beeyan ba gbo nkan, o ye ko koko jokoo lati beere pe se kini yii ri bee.”

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI